Ọmọ Naijiria ẹni ọgbọ̀n ọdun 31 kọ ìyàwó rẹ ara ilu Britain ẹni ọdun méjìdínlaadorin 68 silẹ lẹyin ti wọn de UK.

Obinrin kan ti o dagba ju ọkọ rẹ ọmọ orilẹ-ede Naijiria lọ pẹlu ọdun mẹrindinlọgoji (36) n kigbe fun iranlọwọ lẹyin ti ọkọ naa parẹ, ti o salo mo lowo,ti ko si mọ ibi ti o wa, lẹyin ti o ti darapọ mọ obinrin agbalagba naa ni ilu oke-okun leyin igbeyawo won.

Iya-agba ara ilu Britain ẹni ọdun 68 kigbe soke lẹyin ti ọkọ rẹ, ọmọ Naijiria ẹni ọdun 31, sa lọ lẹyin ti wọn de UK pẹlu iwe-aṣẹ iwọle fun oko-aya (spouse visa)

Dawn Otewell, iya-agba ara ilu Britain ẹni ọdun 68, ti ṣalaye bi ọkọ rẹ ọmọ Naijiria ẹni ọdun 31 ṣe parẹ lẹyin ti wọn gbe lọ si UK pẹlu iwe-aṣẹ iwọle fun oko-aya; eyi ti o jẹ ki ko le pari ilana ikọsilẹ wọn, ti o si tun jẹ ki o ni aniyan nipa ogún awọn ọmọ rẹ.

Dawn, ti o wa lati Dewsbury ni West Yorkshire, pade Bright Emokpae, ti o wa lati Ipinle Edo, lori awọn ohun elo ayelujara bii Tinder ati Plenty of Fish ni ọdun 2021. O sọ pe ni ibẹrẹ, Bright pe ara rẹ ni Brian Thomas, o si sọ pe oun jẹ alamọdaju ti o wa ni ẹgbẹ ọdun 30, ṣugbọn nigba to ya, o jẹwọ pe akẹkọọ nipa aṣa ati aṣọ (fashion student) ni oun, ti o si wa ni aarin ọdun 20 rẹ, lati ilu Benin ni Naijiria.

Bi o tilẹ jẹ pe o purọ fun un, Dawn sọ pe oun nifẹ si i nitori awọn ọrọ ifẹ rẹ ati bi wọn ṣe ma n pe ara wọn lori fidio nigbagbogbo. Wọn wa ṣe igbeyawo ni ile-iṣẹ ijọba ni Nicosia, Cyprus, ni ọjọ 22 Oṣu Kẹta ọdun 2022; lẹyin eyi, Bright pada si Naijiria lati beere fun iwe-aṣẹ iwọle UK fun oko-aya.

Gẹgẹ bi Dawn ṣe sọ, nigba ti wọn fọwọsi iwe-aṣẹ iwọle rẹ ni bii ọdun kan lẹyin naa, o gba a tọwọ-tẹsẹ ni papa ọkọ ofurufu Heathrow, ṣugbọn ibasepọ wọn bẹrẹ si ni bajẹ. O fi ẹsun kan an pe o bẹrẹ si ni yago fun oun, o ma n beere owo lọwọ rẹ nigbagbogbo, o kọ lati ṣe alabapin ninu awọn inawo ile, o si ma n fi owo ranṣẹ si Naijiria nigbagbogbo.

Tọkọtaya naa ya ara wọn sọtọ ni Oṣu Kẹwa ọdun 2023, ṣugbọn wọn tun pada wa papọ ni oṣu mẹfa lẹyin naa lẹyin ti Dawn gba owo isanpada ti o to £63,000 nitori ilana itọju iṣoogun kan ti ko lọ daadaa.

Ọmọ Naijiria ẹni ọdun 31 kọ iyawo rẹ ara ilu Britain ẹni ọdun 68 silẹ lẹyin ti wọn de UKIya-agba ara ilu Britain ẹni ọdun 68 kigbe soke lẹyin ti ọkọ rẹ, ọmọ Naijiria ẹni ọdun 31, sa lọ lẹyin ti wọn de UK pẹlu iwe-aṣẹ iwọle fun oko-aya (spouse visa)Dawn Otewell, iya-agba ara ilu Britain ẹni ọdun 68, ti ṣalaye bi ọkọ rẹ ọmọ Naijiria ẹni ọdun 31 ṣe parẹ lẹyin ti wọn gbe lọ si UK pẹlu iwe-aṣẹ iwọle fun oko-aya; eyi ti o jẹ ki ko le pari ilana ikọsilẹ wọn, ti o si tun jẹ ki o ni aniyan nipa ogún awọn ọmọ rẹ.Dawn, ti o wa lati Dewsbury ni West Yorkshire, pade Bright Emokpae, ti o wa lati Ipinle Edo, lori awọn ohun elo ayelujara bii Tinder ati Plenty of Fish ni ọdun 2021. O sọ pe ni ibẹrẹ, Bright pe ara rẹ ni Brian Thomas, o si sọ pe oun jẹ alamọdaju ti o wa ni ẹgbẹ ọdun 30, ṣugbọn nigba to ya, o jẹwọ pe akẹkọọ nipa aṣa ati aṣọ (fashion student) ni oun, ti o si wa ni aarin ọdun 20 rẹ, lati ilu Benin ni Naijiria.Bi o tilẹ jẹ pe o purọ fun un, Dawn sọ pe oun nifẹ si i nitori awọn ọrọ ifẹ rẹ ati bi wọn ṣe ma n pe ara wọn lori fidio nigbagbogbo. Wọn wa ṣe igbeyawo ni ile-iṣẹ ijọba ni Nicosia, Cyprus, ni ọjọ 22 Oṣu Kẹta ọdun 2022; lẹyin eyi, Bright pada si Naijiria lati beere fun iwe-aṣẹ iwọle UK fun oko-aya.Gẹgẹ bi Dawn ṣe sọ, nigba ti wọn fọwọsi iwe-aṣẹ iwọle rẹ ni bii ọdun kan lẹyin naa, o gba a tọwọ-tẹsẹ ni papa ọkọ ofurufu Heathrow, ṣugbọn ibasepọ wọn bẹrẹ si ni bajẹ. O fi ẹsun kan an pe o bẹrẹ si ni yago fun oun, o ma n beere owo lọwọ rẹ nigbagbogbo, o kọ lati ṣe alabapin ninu awọn inawo ile, o si ma n fi owo ranṣẹ si Naijiria nigbagbogbo.Tọkọtaya naa ya ara wọn sọtọ ni Oṣu Kẹwa ọdun 2023, ṣugbọn wọn tun pada wa papọ ni oṣu mẹfa lẹyin naa lẹyin ti Dawn gba owo isanpada ti o to £63,000 nitori ilana itọju iṣoogun kan ti ko lọ daadaa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *