Ọlọ́pàá Canada mú ọkùnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) fún ẹ̀sùn ìfipábá-ni-lòpọ̀ sí obìnrin méjì, tí kò tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, ní orílẹ̀-èdè Kánádà(Canada).

Ọlọ́pàá Canada mú ọkùnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) fún ẹ̀sùn ìfipábá-ni-lòpọ̀ sí obìnrin méjì, tí kò tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, ní orílẹ̀-èdè Kánádà(Canada).

Wọ́n ti mú ọkùnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan,tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olusegun Onidare, wọ́n sì ti fi ẹ̀sùn kan an fún ìlòkulò ìbálòpọ̀ fífi ipá bá omobìnrin méjì lòpọ̀ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wáyé ní agbègbè Brampton, ní Ontario, orílẹ̀ èdè Kánádà .

Àwọn ọlọ́pàá agbègbè Peel (Peel Regional Police) jẹ́rìí sí àwọn ẹ̀sùn náà nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi sita ní ọjọ́rú, ọjọ́ kejì oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2026 wọ́n sì sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Kẹjọ nígbà tí obìnrin méjì ròyìn pé ọkùnrin kan—tí a kò mọ ẹni tí ó jẹ́ nígbà yẹn—kọlù wọ́n pẹ̀lú ìlòkulò ìbálòpọ̀.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́pàá ṣe sọ, ìṣẹ̀lẹ̀ àkọ́kọ́ wáyé nínú ilé-ìtajà ńlá kan ní ìlú náà nígbà tí ọkùnrin kan—tí wọ́n wá dá mọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gbẹ́ni Olusegun Onidare—kọlù obìnrin kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ wà ní àárín ọmọ ogun ọdún sí ọgbọ̀n (20s) pẹ̀lú ìlòkulò ìbálòpọ̀ nígbà tí ó ń ra ọjà.

Nígbà tó yá ní ọjọ́ yẹn kan náà, ọkùnrin tí wọ́n fura sí náà súnmọ́ ọmọbìnrin kan tí kò tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún ní ibùdó ọkọ̀, ó bá a sọ̀rọ̀ kí ó tó tẹ̀síwájú láti ṣe ìlòkulò ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ .

“Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Kẹjọ, ọkùnrin kan tí a kò mọ̀ kọlù obìnrin méjì pẹ̀lú ìlòkulò ìbálòpọ̀ ní àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní Brampton. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ àkọ́kọ́, obìnrin kan tó wà ní àárín ọmọ ogun ọdún sí ọgbọ̀n ń ra ọjà ní ilé-ìtajà ńlá kan ní agbègbè Dixie Road àti Clark Boulevard nígbà tí ọkùnrin náà súnmọ́ ọn tí ó sì ṣe ìlòkulò ìbálòpọ̀ sí i.

“Nígbà tó yá ní ọjọ́ yẹn kan náà, ọmọbìnrin kan tí kò tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún dúró ní ibùdó ọkọ̀ ní agbègbè Central Park Drive àti Queen Street East nígbà tí ọkùnrin náà súnmọ́ ọn, ó bá a sọ̀rọ̀, lẹ́yìn náà ó sì ṣe ìlòkulò ìbálòpọ̀ sí i,” ni àwọn ọlọ́pàá Peel Regional Police sọ.

Àwọn ọlọ́pàá wá Wọn sì ti fi Ọgbẹni Olusegun Onidare sinu tubu titi di igba ti wọn yóò fi gbọ ọ̀rọ̀ nípa fífún un ni ìwé-àṣẹ lati jáde kúrò ni atimọle (bail).
Ẹ̀yin ènìyàn wa kini ohun tí ẹ bá wa rí sọ sí ọ̀rọ̀ yìí?
Ṣé irú ìwà yìí dá?
#asaketvnews #canada #yoruba #nigeria #everyone #WorldNews

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *