Báyìí ni ọwọ àwọn agbofinro ṣe tẹ Chidi Ebere tó pa ọlọ́kàda tó gbé n’ilu Igbesa Ìpínlẹ̀ Ogun.Èyí ni ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní dédé ago mẹ́jọ òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́rú ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹrin, ọdún 2026,Àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìlú Igbesa ló fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé ọwọ́ ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ogun tẹ arákùnrin Chidi Ebere jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n(27yrs old) tó pa ọlọ́kàda ti ó gbé e. Chidi Ebere dá Sunday Ogbu ọlọ́kàda tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rindínlógójì(36yrs old) dúró pé kí ó gbé òun de ibi tí òun lọ, Bí wọn ń ṣe lọ lọ́nà ni Chidi Ebere ń gbìyànjú láti lọ ọ̀kadà mọ́ Sunday lọ́wọ́ láti jí ọ̀kadà rẹ gbé lọ bí àwọn méjèèjì ṣe ń jíjà káàdì Chidi Ebere fa ohun ìjà kan yọ jáde ó sì gùn Sunday ọlọ́kàda tí ó gbé e. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ nílé iṣẹ́ asaketvnews ni wípé àwọn ó sojumikoro tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ lójú wọn sọ pé wọ́n ké gbàjarè sí ileese ọlọ́pàá to wa n’ilu Igbesa ni kété tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ bi àwọn ọlọ́pàá se dé ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí ṣẹlẹ̀ wọn sáré gbé Sunday ọlọ́kàda náà lọ sí ilé ìwòsàn tó wà ní tòsí fún ìtọ́jú. ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọjọ́ kejì tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ tí ṣe ọjọ́bọ̀ ọjọ́ Kẹ̀sán, oṣù kẹrin ọdún 2026, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ẹpa ò boro mọ́ Sunday ọlọ́kàda tí jáde láyé, wọn ṣàlàyé pé gbogbo igbiyanju àwọn láti dólà ẹ̀mí ọlọ́kàda Sunday pà bó ló jásí látari bí Chidi Ebere to ń lọ́ ọ̀kadà mọ́ lọ́wọ́ ṣe fi ohun ìjà dá patani sì lára.Lójú ẹsẹ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹlẹ̀ ni ọwọ àwọn agbofinro tí tẹ ọ̀daràn Chidi Ebere to pa Sunday ọlọ́kàda náà pẹ̀lú ọ̀bẹ tí ó lò gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà láti fi lọ ọ̀kadà gbà mọ́ Sunday lọ́wọ́ kí ó tó pa á.Ṣùgbọ́n lọ́wọ́ báyìí bí a ṣe ń kó ìròyìn yìí jọ,Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlè Ogun ti gbé ẹjọ́ Chidi Ebere to pa Sunday ọlọ́kàda tí ó ní kí ó gbé òun dé ibi tí òun lọ́, lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá tí ó wà ní Eleweran n’ilu Abẹ́òkúta ìpínlẹ̀ Ogun fún ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn lati tesiwaju nínú ìwádìí àti fún ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tọ̀ jẹ ọ̀daràn náà.
Chidi Ebere fi ọ̀bẹ pa Sunday ọlọ́kàda tí ó gbe e n’ilu Igbesa Ìpínlẹ̀ Ogun












Beckybeauty
O lagbara gan ni, ki Eledumare sanu fun wa 🙏