Trump sọ pé Amẹ́ríkà ti dá ọkọ̀ ojú omi tó ń gbé ẹ̀bùn lọ fún Orílẹ̀ èdè Iran dúró .

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà Donald Trump ni àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà ti dá ọkọ̀ ojú omi China ti o n gbé ẹ̀bùn ń bọ̀ wá fún orílẹ̀ èdè Iran dúró bí àwọn Tehran ṣe ń gbìyànjú láti gba agbára padà nínú àdéhùn jógunómí ọlọ́sẹ̀ méjì tí wọ́n ṣe.

Gẹ́gẹ́ bí Trump ṣe fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ lọ́jọ́ ìṣẹ́gun tíì ṣe ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹrin ọdún 2026, pé Ọkọ̀ ojú omi náà kó àwọn ẹ̀bùn tí kò da ń bọ̀ wá fún orílẹ̀ èdè Iran “Trump ló ṣàlàyé fún CNBC” bẹ́ẹ̀.

Ó ní ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún òun pé òun rò pé ọ̀rọ̀ òun àti Ààrẹ China Xi Jinping jọ́ yé ara wọn ni.

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Ààrẹ China Xi Jinping fi dá Trump lójú tí wọ́n sì jọ ní àjọsọ pé China kò ní kó ohun ìjà ogun fún orílẹ̀ èdè Iran, tó sì jẹ́ wípé alábàṣepọ̀ tó sunmọ ni wọn láti bii ọdún mélòó kan sẹ́yìn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *