Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara tẹ arakunrin tó gbé agbari òkú pamọ sí inú saka gaari tó fẹ́ fi joogun pẹ̀lú àwọn nkan ìjà ogun olóró.
Kọmíṣọ́nà ìpínlẹ̀ Kwara Ojo Adekimi ló fìdí rẹ múlẹ̀ fún àwọn oníwè ìròyìn ní ọjọ́ ẹtì kẹtàdínlógún oṣù kẹrin ọdún 2026, pé ọwọ bá àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn méjì Lukman Abdul-Salam tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí “Ijaya”, àti Aliu Ismaila, tí àpèjẹ́ orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Gambia” bi won se já ṣọ́ọ́bù ní agbègbè Odota n’ilu Ilorin ni bí ti wọn ti kó ọjà tí iye owó rẹ tó 2.5milionu náírà jáde ti àwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn Ẹyẹ yìí jí. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé àwọn méjèèjì paaro pé kii se awon ló jí. Ọlọ́pàá gba ìbọn Ak-47 lọ́wọ́ wọn tí wọ́n fi ń ṣíṣe ọ̀daràn.
Àwọn ọlọ́pàá tún fìdí rẹ múlẹ̀ pé àwọn ni ọjọ́ Kẹ̀wá oṣù kẹrin ọdún 2026, tí àwọn se ise kiri ní gbogbo ọ̀nà Ajase – ipo níbi tí wọ́n ti gba ọkọ rẹ Toyota Previa tí kò ní ìwé ọkọ ti wọn gbé wọ Kwara láti kogi.,nígbà tí wọ́n yẹ ọkọ náà wò ní wón rí méjìdínlọ́gọ́rùn 98, àwọn nkan ìjà ogun tí wọ́n kó pamọ sí inú àpò gaari.
Ọ̀gá ọlọ́pàá ṣàlàyé pẹ̀lú àwọn nkan ìjà ogun tí àwọn gbà lọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn yìí tí ṣe àfihàn pé wọ́n fẹ́ wá ṣe iṣẹ́ ibi ni ìpínlẹ̀ náà ni, àwọn mẹta nínú wọn ni àwọn rí pé wọ́n sise ibi pẹlu awọn ohun ìjà tí wọ́n si gba owó tí iye rẹ jẹ́ 1.3 milionu náírà lọ́wọ́ wọn tí wọ́n fẹ́ fi ra ohun ìjà ogun.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara rọ gbogbo ará ìlú pé àwọn ọ̀daràn tó sá lọ ní àwọn ma mú pátá. Ó tún rọ àwọn ará ìlú pé kí wọ́n wà lójú fò, kí wọ́n sí má tètè fi àwọn ohun tó bá ń ṣẹlẹ̀ nínú ìlú tó ọlọ́pàá létí láti lè ṣe àtìlẹyìn fún àwọn ọlọ́pàá kí wọn lé rí eto àbò tó péye sí orí ara ìlú.












Leave a Reply