Àlàyé tí Netanyahu ṣe rèé lórí àdéhùn jógunómí tó wà láàrin Israeli àti Lebanon Àdéhùn jógunómí yìí bá ọ̀pọ̀ ọmọ Israel lójijì gan-an, ẹ̀ka ìròyìn Israeli kan tó gbajúmò púpọ̀ , kéde pé láàárín ìsẹ̀jú márùn -ún péré ni Olóòtú ìjọba , Benjamin Netanyahu, fi pe ìpàdé àpapọ̀ lórí ààbò , kò sì pẹ́ lẹ́yìn rẹ̀ ni wọn kéde àdéhùn jogún -ósinmi .
Àwọn kan tó tú àṣírí ìpàdé náà tilẹ sọ pé àwọn n mínísítà tó wà níbi ìpàdé náà kò wí nnkan kan, wọn kò fún won láyé láti yan ohun tí wọn fẹ́ .Lójú ọ̀pọ̀ ọmọ ilẹ̀ Israeli , Netanyahu ló ń forí balẹ̀ fún Trump pé kí ogun dúró náà , kódà nígbà tí ohun gbogbo tó yẹ ki wọn ṣe kó tí i jẹ ṣíṣe .
” Bi èèyàn bá fẹ ṣe àdéhùn jógunómí , ó yẹ kó wáyé nípa agbara ni, ko si wa fun àǹfààní àwọn ọmọ Isreali.”Olórí ikọ̀ ológun ní tẹ́lẹ̀ , Gadi Eisenkot, ló sọ bẹ́ẹ̀ .”Ìlànà tí won ba n lo fún wa báyìí ni fífi ipá mú wa lati jẹ́ kogun-o-mi, ni in Gaza, Iran ati Lebanon bayìí . Netanyahu kò mọ bi wọn ṣe n sọ àṣeyọrí ológun di eré fun aráàlú .
“Bí ìròyìn jógunómí ṣe gba gbogbo apá Àríwá ilẹ̀ Israeli kan, bẹ́ẹ̀ ni wọn tún fọn fèrè tantan lẹẹẹmẹta nirọlẹ ọjọ́ ọjọ́rú tíì ṣe ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kẹrin ọdún 2026, láti kilọ àdó olóró tó ṣeé ṣe ko ti Lebanon wá .Bákan náà ni ikọ̀ ojú òfuurufú ilẹ̀ Israel tètè gbéra sọ láti dènà ìkọlù tó ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí ìlú Nahariya, bẹ́ẹ̀ ni àdó olóró ń bù gbàmùGẹ́gẹ́ bí ikọ̀ aláàbò tó ń wa ọkọ̀ agbokuu-gbe àlàyé (Ambulance) ṣe wi , o tó èèyàn mẹta tó farapa kò too di pé òfin jogún omi náà bẹ̀rẹ̀ .Káàkiri Israeli ni wọn ti ń ṣiyèméjì lórí ìdí tí olórí ìlú náà fi tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn onígbèdéke náà .”Niṣe ló dà bíi pé ìjọba purọ́ fún wa.”Akẹ́kọ̀ọ́ ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ Gal, ni Nahariya lo sọ bẹ́ẹ̀ .Ó tẹ̀síwájú pé ;”Ìlérí tí wọn ṣe fún wá ni pé nnkan n máa yàtọ̀ lọ́tẹ̀ yìí , ṣùgbọ́n ó tún jọ pé a tún ń padà síbi àdéhùn jogunomi tí kò tán ìṣòro kankan ní.
Ẹlomi-in ti orukọ tiẹ n jẹ Maor, ẹni ọdún méjìlélógójì to maa n wa tirela, amọ ti àdó olóró ba ilé rẹ lọdun to kọja lo ṣàlàyé bẹẹ.
“Bi a ko ba ṣe e, ko sẹni ti yoo ṣe e. Ìtìjú ni pé won tiẹ dawọ ẹ dúró , òye foju han tẹ́lẹ̀ pé ìyàtọ̀ fẹẹ wa, pẹ̀lú àwọn ohun tí a ti rí ṣe.”
Ibùdó ológun márùn-ún ni Israel ni, ni Gúúsù Lebanon, agbẹnusọ wọn si ni àwọn yóò máa tẹ̀síwájú .
Nígbà tí ó ń ṣàlàyé àdéhùn jógunómí náà , Netanyahu sọ pé “àǹfààní kan ni lati jẹ́ kí àlàáfíà ti yóò wà nínú ìtàn wáyé pẹ̀lú Lebanon”
O si tún sọ pé òun náà ń ṣe àwọn ètò lórí àdéhùn yìí .
Netanyahu ni Hezbollah takú pé ọ̀nà méjì ni ọ̀rọ̀ náà já sí : àkọ́kọ́ ni pé kíkó ọmọ ogun Israeli kúrò ni Lebanon, ikeji si ni pé “Ìlànà ka jọ́ dákẹ́ ogun “.
“Kò sí èyí tí mo gbà wọlé nínú méjèèjì .” A kò ti I ṣe èyíkéyìí nínú méjèèjì . A ṣi máa wà ni Lebanon, níbi tí ààbò ibẹ̀ ti lè . A wà níbẹ̀ a ò ṣì ni kúrò níbẹ̀.”
Bẹ́ẹ̀ ni Netanyahu wí .
Iran ní ti ẹ̀n fẹ́ òpin si ìjà Israeli pẹ̀lú Hezbollah tó jẹ́ èèyàn rẹ̀ ni Lebanon, látìgbà ti won ti fẹnukò si àdéhùn jógunómí i ọlọ́sẹ̀ méjì pẹ̀lú Amẹ́ríkà ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí .
Netanyahu àti àwọn olórí ogun Israel n ri àdéhùn jógunómí ti Trump ṣe pẹ̀lú Tehran bíi pé kò ní ìtumọ̀ si bẹ́ẹ̀ ni Lebanon.
Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọmọ Israeli lo n ri olórí i wọn bii ẹni ti wọn ti kó ni pápá mọ́ra láti gba ohun tí i Amẹ́ríkà bá ń fẹ́ .
Àti pé ohun ti Amẹ́ríkà ń fẹ́ yàtọ̀ sí tàwọn.Nínú fọ́nrán kan tí olórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì fi síta ló ti rọ gbogbo ọmọ Lebanon pé kí wọ́n ma ṣe gba àwọn agbésùnmọ̀mí láyé láti bá ìlú wọn ọjọ́ iwájú àwọn ọmọ wọn jẹ ní gbogbo àwọn alakatakiti wọ̀nyí fẹ́ bá ìlú wọn jẹ́ ti wọn fi pa mọ síbẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ burúkú.






Leave a Reply