Àwọn agbesunmobi yinbon pa ìyá àti ọmọ rẹ̀ obìnrin lójú ẹsẹ bí wọ́n ṣe yawọ inú oko ọ̀sìn Adìẹ ni agbègbè Igushin Ala apá àríwá Akure (Akure North) ni ìpínlè Ondo.Tí won si tún gbìyànjú láti jí àwọn ènìyàn gbé.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ nílé iṣẹ́ wa asaketvnews ni wípé ìkọlù yìí wáyé ní ọjọ́bọ̀ (Thursday) ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹrin ọdún 2026, ní agbègbè Igushin Ala ni apa àríwá Akure. Ìròyìn fìdí rẹ múlẹ̀ pé àwọn agbesunmobi tí wọ́n tó márùn-ún níye wí wọn yawọ oko ọ̀sìn Adìẹ náà tí wọn sì da ìbọn bolẹ̀ tí èyí sì fa ìpayà fún àwọn òṣìṣẹ́ inú oko ọ̀sìn Adìẹ náà lójú ẹsẹ nibẹ ni wọn pa ìyá tí ó ní oko ọ̀sìn Adìẹ àti ọmọ rẹ̀ obìnrin, bákan náà ni wọ́n gbìyànjú láti jí àwọn ènìyàn gbé nínú oko ọ̀sìn Adìẹ bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe n lọ lọ́wọ́.
Sùgbọ́n nígbà tí ó di ọjọ́ kejì tí ṣe ọjọ́ ẹtì ọjọ́ Kẹ̀wá oṣù kẹrin ọdún 2026, tí ìkọlù yìí wáyé ní Agbẹnusọ fún iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo Abayomi Jimoh se àpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà pé ó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ìpayà aburú gidi. Ó tesiwaju pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí ó ṣẹlẹ̀ ni agbègbè Igushin Ala apá àríwá Akure níbi tí àwọn agbesunmobi tí yinbon pa ìyá àti ọmọ rẹ̀ obìnrin nínú oko ọ̀sìn Adìẹ.
Agbenusọ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn dọ́là ènìyàn méjì tí àwọn agbesunmobi fẹ́ ji gbé.
Jimoh, ṣàlàyé wípé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ń gbìyànjú láti rí pé àwọn yóò mú àwọn ọ̀daràn náà tí àwọn yóò sì fi ìyà tí ó tọ́ jẹ wọ́n.
Agbenusọ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo wá rọ gbogbo ará ìlú pé kí wọ́n fọwọ́sowópọ̀ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá kí wọn sì ma tètè fi àwọn ohun tó bá sẹlẹ nínú ìlú tó àwọn ọlọ́pàá létí. Ó sọ wípé ìwádìí ń lọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.












Beckybeauty
Where is this country heading to now