Àwọn Agbéṣùmọ̀mí yawọ ìlú Rafiu Ajakaye olórí àwọn oníròyìn fún Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara.Wón jí ènìyàn mọ́kànlá gbé lọ nínú ìlú Alabe, Babanla àti Kajola ijoba ìbílẹ̀ Ifelodun Kwara.
Ènìyàn méjì ni àwọn agbesunmobi jí gbé n’ilu Alabe to jt ìlú Rafiu Ajakaye , bákan náà ni wọn ji ènìyàn méjì mìíràn gbé nínú ìlú Babanla, wọ́n tún yawọ ìlú Kajola wọn ji ènìyàn méje gbé lọ nibe lónìí tó jẹ́ ọjọ́bọ̀, ọjọ́ ketalelogun oṣù kẹrin ọdún 2026.
Ọ̀kan lára àwọn ará ìlú , ti o ba oníròyìn sọrọ lori ipo ti ilu naa lọ́wọ́ bí àwọn agbésùnmọ̀mí ṣe yawo ìlú náà sọ pé nínú ìbẹ̀rù ni àwọn ará ìlú wà ,tí ó jẹrisi pé ènìyàn mọ́kànlá ni wọ́n jí gbé lọ.
Bí àwọn agbésùnmọ̀mí ti ṣe ń ṣe ikọlu náà lojoojumo ti fa ibẹru bojo ainifokabale fún àwọn olùgbé ni gbogbo agbègbè ni Ipinle Kwara, paapaa ni awọn agbegbe igberiko laarin kwara guusu, nibiti awọn olugbe ti ń kú leralera nipa bí àwọn agbésùnmọ̀mí ṣe kọlu àwọn ará ìlú àti àwọn awọn ọmọ ológun ni Kwara.
Ọ̀kan lára àwọn ẹlẹ́ṣọ aabo kan tun fi idi ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún oniroyin , ti o jẹrisi bí awọn ikọ̀ agbésùnmọ̀mí ṣe kolu àwọn káàkiri gbogbo agbègbè mẹta náà .
Títí di àsìkò tí a fi n gbé ìròyìn yìí síta , nílé isẹ wa asaketvnews ko tii si ọrọ kan ti ijọba ìpínlẹ̀ Kwara tabi awọn iléeṣẹ́ ọlọ́pàá eléso ààbò kan sọ nipa ìkọlù tabi ṣe akitiyan lati gba awọn ti o FARAPA àti àwọn tí wọ́n jí náà sílẹ̀ ati lati mu àwọn ti wọn huwa ọ̀daràn náà .
Awọn olugbe ni awọn agbegbe ti o kan tí won se ìkọlù ni nínú ìbẹ̀rù,ní àwọn n gbe báyìí, wọn àwọn ro ìjọba ati awọn ile-iṣẹ ẹlẹ́ṣọ aabo lati da si ni kíákíá ati lati lé má je ki iru ìkọlù náà tún wáyé.












Leave a Reply