Ènìyàn márùn ni àwọn agbesunmobi tún ti pa lára wọn ni T. Dollar, ní Igbatoro ni ìpínlẹ̀ Ondo, Àwọn ará ìlú gbegi di òpópónà ọ́fíìsí Gómìnà ni Akure.

Àwọn ará ìlú se ìfẹ̀hónúhàn láti ké gbàjarè sì etí ìjọba bí àwọn agbesunmobi ṣe n pa àwọn ènìyàn lójoojúmọ́ ni agbègbè Ilado, Igushin, Igbatoro apá àríwá Akure ní Ìpínlẹ̀ Ondo.

Inú ìpayà iforo ẹ̀mí, ìbànújẹ́ ni àwọn ará ìlú, imafon, Igushin, Ilado, Igbatoro nipinle Ondo wà báyìí látàrí bí àwọn agbesunmobi tún ti ṣe pa ọ̀dọ́ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ T dollar. Ikú T dollar pẹlu awọn ènìyàn márùn-ún mìíràn tí àwọn agbesunmobi tí kọ́kọ́ pa ló mú kí àwọn ará ìlú ya síta láti ṣe ìfẹ̀hónúhàn lónìí ọjọ́ Abamẹta, ọjọ́ kọkànlá, oṣù kẹrin ọdún 2026. Láti lè fòpin sí ìkọlù àti ìjínigbé tó ń wáyé lójoojúmọ́ náà àti láti ké sí ìjọba láti lè wá ojútùú sì ètò abo to mẹ́hẹ lo jẹ ki awon olugbe agbègbè yìí gbegi di òpópónà tó lọ sí ọ́fíìsì Gómìnà, nílùú Akure láti fi ẹ̀hónú hàn.

Lásìkò ìfẹ̀hónúhàn náà, ní àwọn obìnrin, ọkùnrin àti àwọn ọ̀dọ́ gbogbo àwọn olùgbé agbègbè ìlú náà gbegi Dínà òpópónà náà, tí àwọn ọlọ́kọ̀, ọlọ́kadà kò sí rí ibi gba kọjá. Fọ́nrán ṣe àfihàn rẹ bí àwọn ará ìlú ṣe ya sí pópónà tó lọ sí ọ́fíìsí Gómìnà ni Akure ti won si se ìfẹ̀hónúhàn bí àwọn agbesunmobi ṣe ńṣe ìjàmbá ńlá fún wọn ní gbogbo agbègbè Igbatoro.

Ọ̀kan lára àwọn olùfẹ̀hónúhàn ṣàlàyé bí àwọn agbesunmobi ṣe ń pa àwọn ènìyàn lójoojúmọ́. Ó ṣe àlàyé bí wọn ṣe pa T dollar pe lásìkò tí T dollar n gbe ọkọ rẹ̀ wọlé ní àwọn agbesunmobi ṣe ìkọlù sí ó sọ pé ilé àwọn méjèèjì fẹ̀gbẹ́ tí ara wọn ni ati wípé nise ni àwọn agbesunmobi yìí yinbon fún T dollar laya nígbà tí ó ń wá ọkọ rẹ wọlé. Ó ní T dollar pè fún ìranlowo ṣùgbọ́n kò ṣe ẹni tí ó lè jáde síta ni àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀, nitori nise ni àwọn agbesunmobi ń náà yinbon lákọlákọ ni.

Ó ṣàlàyé pé àwọn ẹlẹ́sọ́ àbò Àmọ̀tẹ́kùn to wà ni àyíká kò yọjú, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí àwọn adari ìlú pé àwọn Amotekun, wọn sọ fún pé àwọn kò ní ọta nínú ìbọn àwọn wípé ìdí tí àwọn kò fi lè yọjú sí àwọn agbesunmobi náà nìyẹn. Ó ní ènìyàn márùn-ún ni wọn ti pa nínú ọ̀sẹ̀ yìí, ó ní nínú ọ̀sẹ̀ kò sì ọjọ́ kan tí àwọn agbesunmobi kò pa eniyan nínú ìlú Igbatoro, ó tẹ̀síwájú pé ní oṣù tó kọjá ní àwọn agbesunmobi da màlúù wọ inú oko òun ti wọn si jẹ́ Ẹ̀gẹ́ tí òun gbìn sínú oko bí àwọn se gbé ọ̀rọ̀ náà de ọdọ àwọn olopaa òní kò sí nkankan ti àwọn olopaa rí ṣe sí ọ̀rọ̀ náà.

Ó ní o yẹ ki àwọn ìjọba kó ohun ìjà gidi sì ọwọ àwọn ẹlẹ́sọ́ àbò, nítorí pẹ̀lú àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kò yẹ kí àwọn ará ìlú nílò iranlowo àwọn ẹlẹ́sọ́ àbò kí àwọn ẹlẹ́sọ́ àbò má sọ wipe kò sì epo nínú ọkọ, bákan náà ló ṣàlàyé pé àwọn ohun ìjà tó wà lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́sọ́ abo kéré sì èyí tí ó wà lọ́wọ́ àwọn agbesunmobi.

Bí ẹ kò bá ní gbàgbé ni gbogbo ọdún tó kọjá bayii náà ni àwọn agbesunmobi ṣe ńṣe ìkọlù sí agbègbè Familugba Igbatoro tó jẹ́ pé iye àwọn ènìyàn tí àwọn agbesunmobi pa nínú ìlú náà ni ọdún tó kọjá pọ̀ níye.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *