Àwọn Agbéṣùmọ̀mí ti jí Ọgbẹni Bamsa Remilekun Daniel gbé nínú oko rẹ̀ ni Ègbé okun land.
Ìròyìn fidi e mule pé Ogbeni Bamsa Remilekun Daniel ni àwọn agbésùnmọ̀mí ji gbe ni Egbe, ijoba ibile Yagba West ni ìpínlẹ̀ Kogi.
Ìròyìn fi to wa leti wípé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ ni nkan bi aago mesan àárọ̀ ọjọ́rú ọjọ́ kọ̀ọ̀kandinlógbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 2026 yìí , , , lágbègbè oko Airfield ni Egbe.
Awọn ara ìlú sọ pé agbésùnmọ̀mí náà ,jí arákùnrin náà gbé nínú oko rè nígbà tí ó ń ṣíṣe ni owurọ oni.
Àwọn ènìyàn tí o wa ni ayika iṣẹlẹ náà wa ṣàlàyé pé títí di àkókò yìí Àtẹ̀jáde kan kò ti jáde láti iléeṣẹ́ àwọn ẹlẹ́ṣọ àbò agbègbè náà .
Awọn olùgbé agbègbè náà n pe fun igbese ni kiakia bi àwọn ifiyesi lórí àìsí ètò àbò tó péye ti ń peléke si ni agbègbè náà.












Leave a Reply