Fatimo ni agídí púpò ni a ṣe pa á nínú àhámọ́ , agbéṣùmọ̀mí pa ọkùnrin oníṣòwò àti ọmọ rẹ lẹ́yìn N12m

Lẹ́yìn owó ìtúsílẹ̀ N12 mílíọ̀nù àwọn agbésùnmọ̀mí PA arákùnrin oníṣòwò ńlá kan àti ọmọ rẹ̀ n’ilu Abuja.
Fatima jẹ́ ọmọ ilé ìwé gíga Fásitì ti ìlú Abuja kí àwọn agbésùnmọ̀mí tó pa òun àti bàbá rẹ̀
Ìròyìn tí ó tẹ wà lọ́wọ́ nílé ìṣe ìròyìn Asaketvnews ni pé bí arákùnrin oníṣòwò tí orúkọ rẹ ń jẹ Muhammad Shuaibu àti ọmọ rẹ̀ obìnrin yìí ṣe lọ ń ta ọjà ni ilé ìtajà wọn tí ó wà ní ọjà Dei-Dei tó wà ní ìjọba ìbílè Bwari ní FCT Abuja tí ṣe olú ìlú Nàìjíríà,ni àwọn agbésùnmọ̀mí afemisofo ṣe ikulo si wọn.
Àwọn agbésùnmọ̀mí afẹ̀míṣòfò pa oníṣòwò Muhammad Shuaibu àti ọmọ rẹ obìnrin ọmọ ọdún mọ́kàndílógún(19) ti orúkọ ọmọ ń jẹ Fatimo Muhammad, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó tí ó tó N12milionu tí àwọn agbésùnmọ̀mí tí gba lọ́wọ́ àwọn ẹbí. gẹ́gẹ́ bí ohun tí a gbọ́ ni wípé láti ọjọ́ kẹta, oṣù Kejìlá ọdún 2025, ní àwọn agbesunmobi tí ji arákùnrin oníṣòwò yìí àti ọmọ rẹ̀ gbé. Ọkàn lára àwọn ẹbí arákùnrin náà tó fi idi ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ṣe àlàyé wípé lọ́jọ́ tí àwọn agbésùnmọ̀mí yawo àgbègbè tí wọn ti jí arákùnrin yìí gbé wọn da ìbon bole to fi jẹ pe ko si enikankan tàbí eléso abo kan tí ó yọjú sí wọn fún wákàtí melo kan tí wọn fi ṣe ìkọlù náà. Leyin náà ni agbesunmobi bèrè fún owó ìtúsílẹ̀ Shuaibu àti ọmọ rẹ̀ ọmọbìnrin Fatimo tí àwọn ẹbí sì gbìyànjú láti ṣe akitiyan, wọn tá gbogbo àwọn ọjà tí arákùnrin oníṣòwò yìí ni sì ilé, itaja,àti ilé itaja ni wọn tá papọ mo ọjà inú rẹ nígbà owó kò tíì pé àwọn agbesunmobi sọ fún àwọn ẹbí pé kí wọ́n lọ tá ilé arákùnrin òun kì wọn kó owó rẹ wà fi gba ènìyàn wọn silẹ ni ahamo, ṣùgbọ́n ohun tí ó wà ṣeni laanú ni pé lọ́jọ́ tí àwọn ẹbí gbé owó toku lọ́ fún wọn, lẹ́yìn náà ni àwọn agbesunmobi tẹ́wọ́ gba owó tán wọn sọ fún ẹni tí ó gbé owó lọ wípé kí ó pẹsẹ̀ fún ijalo kí ó kúrò ní àyíká àwọn, wọn sọ wípé arákùnrin oníṣòwò Shuaibu tí àwọn ji tí di olóògbé leyin àìsàn ranpe die tí ó ṣe é ní ahamo àwọn. leyin oṣù meta tí bàbá àti ọmọ tí wà ni ahamo wọn, wọ́n gba N12milionu tí àwọn ẹbí gbé lọ agbésùnmọ̀mí pa Fatimo won ni ọmọ obìnrin náà ní agídí púpò. Àwọn ẹbí ṣàlàyé pé gbogbo igbiyanju àwọn láti bá Oga ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Niger sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n wọn kò gbé èrò ibanisoro wọn bákan náà ni wọ́n nigbogbo ìgbìyànjú láti pé alukoro ileese ọlọ́pàá Wasiu Abiodun pàbó lo ja.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *