Ìyá àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pàdánù ẹ̀mí wọn bí wọn ṣe n rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ Mecca.

Àwọn Àjọ tó ń ṣe agbeteru ìrìnàjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ Mecca tí ìpínlẹ̀ Kano pilgrim tí kẹ́dùn ìyá àti ọmọ tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ijamba ọkọ tó wáyé ní pópónà Rimin Gado -Kano.

Àjò tó mójúto ìrìnàjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ tí ìpínlẹ̀ Kano bá ebi àwọn olóògbé ìyá àti ọmọ ọkùnrin tó kú nínú ijamba ọkọ náà kẹ́dùn.

Ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní pópónà Rimin Gado – Kano lọ́jọ́ kejìlélógún oṣù kẹrin ọdún 2026 yìí, nínú ijamba ọkọ tí ìyá àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tí pàdánù ẹ̀mí wọn, ìyá ni orúkọ rẹ ń jé Hadiza Garba ẹni ọdún mẹ́tàlẹ́láàdórín(73)ti ọmọ rẹ ọkùnrin Alkasim Ibrahim Walawa je eni ọdún méjìdínláàdọ́ta(48) Hadiza tó jẹ́ ìyá fi ọmọ márùn-ún silẹ sáyé, tí ọmọ rẹ ọkùnrin sì fi ìyàwó méjì pẹ̀lú ọmọ méje sílè sáyé, wọ́n jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Walawa ni ijoba ìbílẹ̀ Kabo ni ìpínlẹ̀ Kano, àwọn méjèèjì ìyá ati ọmọ ọkùnrin rẹ tí wọ́n jọ ń rìn irinajo lọ sí ilẹ̀ mímọ́ Mecca ló pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ijamba ọkọ. Àwọn tó ń mójú ìrìnàjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ Mecca àti àwọn òṣìṣẹ́ wọn ba ebi àwọn olóògbé náà dẹkùn tí wọ́n gbàdúrà pé kí Ọlọ́run pa gbogbo àṣìṣe wọn rẹ, kí Ọlọ́run sì fi ọrùn kẹ́ wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *