Ọwọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ti tẹ ọlọ́pàá tó n gba owó rìbá lọ́wọ́ àwọn awakọ̀, onikẹ̀kẹ́ maruwa, ọlọ́kadà ní Idimu L’eko.

Ọwọ́ Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Èkó ti tẹ ọlọ́pàá 👮👮‍♂️ tó ń gba rìbá lọ́wọ́ àwọn oni Kẹ̀kẹ́nape ,awakọ̀,ọlọ́kadà ,🚴‍♂️ onímaruwa 🚙 ní agbègbè Idimu Ìpínlẹ̀ Èkó .

Lẹ́hìn tí fọ́nrán kan jáde síta tó ṣe àfihàn ẹ̀rí Ìdánilójú níbi tí 👮 ọlọ́pàá yìí ti dá ọkọ̀ Arakunrin kan dúró tí arákùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣe fọ́nrán tó ń kígbe wípé Lẹ́hìn tí gbogbo ìwé ìrìnnà ohun pé tí ohun kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ kọ̀ọ̀kan ṣùgbọ́n kí ọlọ́pàá 👮náà lè gba owó lọ́wọ́ awakọ̀ yìí ló bá ní kí ló dé tí awakọ̀ yìí ṣe kun ọkọ̀ rẹ̀ tí ní àwò “Colour ” tí kò bójú mu 🚙 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí awakọ̀ náà sọ wípé ọlọ́pàá náà yari wípé àwọ̀ (colour )tí wọ́n fi kun ọkọ̀ náà jẹ́ ( grey).

Ṣùgbọ́n (ash) ni wọ́n kọ sínú ìwé ìrìnnà ojú pópónà ọkọ̀ náà , ọlọ́pàá náà sì gbìyànjú láti mú awakọ̀ yìí tí ó sì ní kí awakọ̀ náà san owó 30,000 ṣùgbọ́n nígbà tí ó yá ní ọlọ́pàá bá ní kí awakọ̀ mú 10,000 wá , nítorí colour ọkọ̀ náà ni ò ṣe fẹ́ gba owó.

ṣùgbọ́n báyìí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti fi Ọwọ́ òfin mú ọlọ́pàá náà ó sì ti wà ní Àhámọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá. ọ̀gá ọlọ́pàá sọ pé wọ́n yóò sì fi ìjìyà tí ó tọ́ jẹ́ pẹ̀lú ìwà burúkú tí Ọlọ́pàá náà hu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *