Ọwọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti tẹ àwọn agbésùnmọ̀mí afẹ̀míṣòfò afurasí fúlàní ni ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́

Ọwọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti tẹ àwọn agbésùnmọ̀mí afẹ̀míṣòfò afurasí fúlàní darandaran mẹ́ta tó ṣékupá àgbẹ̀ kan nínú rẹ̀ ọ̀gbẹ́ni Kẹhinde lọ́jọ́ Ìsinmi, ọjọ́ Kàrún un, oṣù kẹrin ọdún 2026 yìí, ní agbègbè Igbopupa Yawota ìlú Ogbomoso.
Ìròyìn tí a gbọ́ nílé iṣẹ́ Asaketvnews ni wípé, àgbẹ̀ náà lọ wo àwọn ẹ̀gẹ̀ oko rẹ̀ ni kí àwọn Fulani darandaran náà tó kọlù tí wọ́n sì ṣékupá.
Ìṣẹ̀lẹ̀ náà ló wáyé lágbègbè Igbopupa Yawota lẹ́gbẹ̀ ìlú Alawusa ni ìjọba ìbílẹ̀ Orire L’ogbomoso.
Àwọn Agbésùnmọ̀mí afurasí ọ̀daràn darandaran náà ni wọ́n fẹ́ fi àwọn màlúù wọn jẹ oko olóògbé Kehinde àgbè náà lọ́jọ́ ìsinmi, ọjọ́ Kàrún un, oṣù kẹrin ọdún 2026 yìí, tí àgbè olóògbé Kẹhinde sì kọ̀ jálẹ̀.
Àgbẹ̀ náà ṣeré lọ sí oko rẹ láti lọ wo àwọn ohun ọ̀gbìn ẹ̀gẹ̀ tí ó gbìn sí oko ni nǹkan bí dédé ago mẹrin ìrólẹ́ ọjọ́ ìsinmi ọ̀hún tí ó sì bá àwọn Fulani darandaran náà nínú oko rẹ̀, kí àwọn afurasí darandaran náà tó ṣa ní Àdá pa sínú oko rẹ̀. Iléeṣẹ́ Asaketvnews gbọ́ pé wọn gbìyànjú láti gbé àgbẹ̀ ọ̀gbẹ́ni Kehinde náà lọ sí ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí àwọn Fulani darandaran náà tí ṣa ni àdá tán, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ẹpa ò bóró mọ́, àgbè náà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ní bíi ago méjì àárọ̀ ọjọ́ Ajé.
Ọwọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti tẹ àwọn Fulani darandaran mẹta náà tí wọn sì wà ní àhámọ́ àtìmọ́lé ọlọ́pàá lórí Ìṣẹ̀lẹ̀ náà báyìí.
Kini ohùn tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ri sọ si ìṣẹ̀lẹ̀ náà :
Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olayinka Alayande fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn akọ̀rọ̀yìn. Alayande sàlàyé pé ní kété tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní wọn ti fi tó àwọn agbòfinró to wà ní ìjọba ìbílè Orire L’ogbomoso létí. Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tesiwaju pé ọgbẹ́ pọ̀ lara olóògbé Kẹhinde àgbè náà, eleyii lo sì faa tó fi pàdánù èmi rẹ. Ó sọ pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlè Ọ̀yọ́ tesiwaju ninu ise ìwádìí wọn ti yóò sì fi imú àwọn Fulani darandaran náà dánrin.
TI ẹ ko ba ni gbàgbé kii se ìgbà àkọ́kọ́ tí irúfé ìṣẹ̀lẹ̀ bayi yóò sele n’ilu Ogbomoso rèé.
Ní Ọdún 2024, ní àwọn Fulani darandaran kan ṣékupá pásítò Segun Adegboyega ninu oko rẹ tó wà lágbègbè Gege, tó wà ní òpópónà Ogbomoso sí Ìlú Iseyin lásìkò to ń ṣe ikilọ fún àwọn fúlàní darandaran to da Máàlù je oko rẹ kì wọn tó gùn lọ́bẹ̀ pa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *