Ọwọ́ tí tẹ àwọn agbésùnmọ̀mí 33 tí wón ṣe ìkọlù sí Ilé ìjọsìn CAC òkè ìṣẹ́gun Eruku Kwara .

Tí ẹ bá ní gbàgbé, ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kọkànlá ọdún 2025, ní àwọn agbesunmobi yawọ ilé ìjọsìn CAC òkè ìṣẹ́gun Eruku Kwara ,tí wọn sì pa ènìyàn mẹta lójú ẹsẹ, wọ́n sì tún ji àwọn ará ilé ìjọsìn méjìdínlógójì gbé lọ.

Ni ọjọ́ ajé, ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹrin ọdún 2026, ni alukoro ọlọ́pàá Nàìjíríà, Anthony Placid, fi ìròyìn náà lédè.

Alukoro ileese ọlọ́pàá Nàìjíríà Anthony Placid kéde rẹ̀ pé ọwọ tí tẹ àwọn agbesunmobi mẹ́tàlélọ́gbọ̀n 33 ti wọn se ìkọlù sí Ilé ìjọsìn CAC òkè ìṣẹ́gun Eruku Kwara.

Ó ṣe àlàyé pé láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí ṣẹlẹ̀ ni ileese ọlọ́pàá ti wá àwọn odaran afemisofo náà, ó ni bí àwọn olumoye àti àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyé ń ṣe ìwádìí náà ni àwọn ọlọ́pàá náà ṣe ìwádìí. Ṣùgbọ́n ọwọ àwọn tí tẹ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n àwọn ọ̀daràn Ó ṣàlàyé pé oríṣiríṣi ibùdó ní àwọn tí mú wọn.

Ó ní wọn mú àwọn kan ni Gbugbu, Ora-Ago, Babanla, Kaiama, Awi, Patigi,okeode, ti awon sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìjà olóró bí: AK-47, àti ohun ìjà tí wọn fi ń já ọkọ ofurufu bọ́, (32 round of 7.62mm live ammunition,), (5 walkie talkie) ati ọ̀pọ̀ aso ogun (camouflage uniforms) lọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn agbesunmobi náà.

Orúkọ àwọn agbésùnmọ̀mí 33 tí ọwọ́ iléeṣé ọlọ́pàá Nàìjíríà tẹ̀ náà ni yìí pẹ̀lú ọjọ́ orí wọn: Abubakar Usman, Siddi, 26; Ibrahim Sa’idu, alias Idi Soho, 35; Adamu Mohammad, aka Baushe/Dogo, 58; Abdullahi Abubakar, aka Bature, 35; Abubakar Abdullahi, aka Turke, 35; Yusufa Isah, aka Munyaye, 50; Zubairu Abubakar, 35; Shaibu Usman, 35; Mohammed Lawai, aka Jalel, 40; Dahiru Adamu Mohammedu, 50, and Mohammadu Audu, aka Alti, 40. Dahiru Alh Ahmadu, 25; Iliyasu Umar, aka Magaji, 38; Usman Alh Mati, aka Saidu, 30; Umar Mohammed, aka Mulandan, 25; Shehu Usman Mohammedu; Umar Mohammed Jos, 25; Mohammadu Ali, aka Jabbi/Ruwa, 30; Abubakar Mamman, 28; Mohammadu Alti, 32; Idris Auwal, aka Samaila, 26; Ajiboye Biodun, 20; Lawali Shehu, 32; Mohammadu Sani, aka Kachalla Ruga, 65; Musa Ado, aka Maidu, 65; Abubakar Adamu, aka Buba, 26; Mohammadu Zangina, aka Zangina, 23; Abubakar Shaibu, aka Jijji, 20; Mohammadu Salihu, aka Fulani, 25; Mohammadu Musa, aka Musa, 23; Abubakar Sani, aka Siddi, 25; Yusufa Isah, aka Leriya, 22; and Mohammadu Ibrahim, aka Iro, 21.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *