Àwọn agbesunmobi ikọ̀ bokoharam pa Ọ̀gágún O. Braimah Alakoso ẹgbẹ́ ọmọ ogún Naijiria tì o jẹ́ ẹ̀ka 29 ikọ̀ ọgbà ológun tó wà ní Benisheikh ni ìjọba ìbílẹ̀ Kaga ìpínlè Borno. Àwọn agbésùnmọ̀mí yawọ ọgbà ológun Benisheikh ni Ìrọ̀lẹ̀ ọjọ́rú ojo kẹjọ osu kerin 2026, ohun tí a gbo ni pé wọn da ìbon bole ti àwọn ológun to wá lenu iṣẹ́ nínú ọgbà ogún náà sì koju wọn, ṣùgbọ́n omi poju ọkà lọ fún àwọn ọmọ ogún Naijiria nítorí pé àwọn ohun ìjà oloro tó wà lọ́wọ́ àwọn agbesunmobi ju ti àwọn ọmọ ogún Nàìjíríà tí wọn ba lenu ise ọgbà ogún Benisheikh náà. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe fìdí rẹ múlẹ̀ pé àwọn agbesunmobi dáná sun ọgbà ológun Benisheikh bí ìkọlù náà ṣe ń lọ lọ́wọ́, tí wọn tun ba ọpọlọlop àwọn irinṣẹ́ ológun to wá nínú ọgbà náà je, wọn pa Ọ̀gágún Braimah lenu ise nínú ìkòlu naa. Bákan náà ni ìròyìn tún fìdí rẹ múlè pé wọ́n tún pa Ọ̀gágun Imam nínú ìkòlu náà , ọ̀pọ̀ àwọn agbesunmobi náà ni àwọn ọmọ ogun Naijiria pa bí wọn ṣe koju ìbon sì ara nínú ìkọlù náà tó wáyé ní ọgbà ológun tó wà ní Benisheikh ni ijoba ibile Kaga ipinle Borno, ṣùgbọ́n ní àkókò tí a ń kó ìròyìn yìí jọ ileese ológun Naijiria kò ti sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù náà. Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun àti àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ abẹ̀lé tí fìdí rẹ múlẹ̀ níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù náà wáyé. Tí ẹ kó bá ní gbàgbé nínú oṣù kọkànlá ọdún 2025 ni àwọn agbésùnmọ̀mí ikọ̀ bokoharam yìí pa Ọ̀gágun Musa Uba lẹ́nu isẹ́ nígbà tí ó ń kó àwọn ọmọ ogún ń lọ fẹ́ lọ kojú àwọn agbesunmobi ni zamfara.
Àwọn Agbéṣùmọ̀mí Bokoharam tún ti pa ọ̀gágun O. Braimah lénu isẹ́ bí wọn ṣe ṣe ìkọlù sí ọgbà ológun Benisheikh Borno












Leave a Reply