Àwọn ìdílé ọmọ òye Fagbemirokun àti Aribile fún ìjọba Ọ̀sun ní gbèdéke ọjọ́ méje péré láti rọ Apetu tí Ipetumodu Ọba Oloyede tó wà lẹ́wọ̀n L’ámẹ́ríkà lóyè. Wọn ní bá wo ni ìlú a ṣe wà tí kò ní sí ọba láti ìgbà tí ọba ìlú náà tí wà lẹ́wọ̀n ni Amẹ́ríkà kò sì ẹni tí ó ń tuko ìlú náà, àti wípé sebi àwọn a ṣe ma wò’ran rèé fún iye ọdún tí ọba Oloyede fẹ́ ló lẹ́wọ̀n tí orí apere ìlú Ipetumodu asofo.Wọn sọ pé bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn yìí àti ìwà jìbìtì tí ọba Oloyede hu yìí jẹ ohun ti tàbùkù ìlú Ipetumodu àti ìtẹ́ ọba ṣùgbọ́n síbẹ̀ síbẹ̀ a ò lè fi ori ite ọba Ipetumodu silẹ kò sofo.
Àwọn Ìdílé ọmọ oyè méjì pẹ̀lú àwọn afọbajẹ ní ìlú Ipetumodu ni ipinlẹ Ọṣun, ti fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀sun , Ademọla Adeleke ni gbèndeke ọ̀sẹ̀ kan péré láti rọ Ọba ìlú náà , Apetu ti ìlú Ipetumodu lóye kò sí kede apere ọba ilu naa gẹ́gẹ́ bí èyí tó ṣọ̀fọ̀ ki wọn le bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́sẹ̀ láti yan ọba tuntun níbẹ̀ .Àwọn aṣojú ilé òye méjèèjì, Aribile ati Fagbemirokun pé ìpàdé pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn ní ìlú Ipetumodu, níbi tí wọn ti fi èrò wọn hàn, Bákan náà ni wọn tún fi ẹ̀sùn kan ìjọba ìpínlẹ̀ Ọṣun pé o mọ̀ọ̀mọ̀ n fi ẹsẹ falẹ lórí ìgbésẹ̀ láti rọ́pò ọba Joseph Oloyede ti wọn ran lẹwọn lórílẹ̀ èdè Amẹrika lórí ẹ̀sùn ìwà jìbìtì owó COVID19 tí wón kan Alapetu tí ìlú Ipetumodu tí sì wá ní ẹ̀wọ̀n LÁMẸ́RÍKÀ lọ́wọ́ báyìí .
Bí ẹ kò bá gbàgbé , Ọba Oloyede tó jẹ ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́ta di èrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn ti Onidajọ Christopher A. Boyko rán an lẹwọn kó lọ fi aṣọ péńpé roko ọba fún oṣù mẹrindinlọgọta. Wọn ní o jẹbi ẹ̀sùn lílu jìbìtì pẹ̀lú ètò ẹyawo COVID-19 ti wọn gbé kalẹ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn okoowoò kékeré tó fara kaasa lásìkò àjàkálè àrùn náà .Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìtẹ Apetumodu tí n mú ipenija bá ìlú Ipetumodu –
Ìdílé Oyè ìlú IpetumoduỌmọọba Dele Oyebade tó ka ìwé àpilẹ̀kọ wọn lásìkò ìpàdé náà sọ pé ìwé ìdájọ́ ile ẹjọ́ náà ti ìjọba béèrè fún ti wà lọ́wọ́ àwọn , àwọn sì ti fún ìjọba , síbẹ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀sun kọ̀jálẹ̀ láti jáwé sobi yiyọ ọ.Ó ni ìgbẹ́sẹ̀ yìí ti ta ẹrẹ̀ àti ìwọ̀sí si apeere náà ati gbogbo ìdílé oyè nínú ìlú náà.
Lónìí ni Ọjọbọ̀.ti a sì n fún ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀sun ni gbendeke ọjọ meje láti gbé ìgbẹ́sẹ̀ lórí ohun ti a ń béèrè fun, kí wọn si kéde ṣiṣofo orí ìtẹ́ ọba Apetumọdu.”Ó ni ìpèníjá ńlá ni ìlú náà n kojú báyìí nítorí i àwọn awuyewuye tó so rọ mọ àga apetumọdu lọ́wọ́ yìí .ìdílé ọmọ òye fún ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀sun ni gbèdéke ọjọ́ méje láti wá ojútùú sì ite ọba Alapetu tìlú Ipetumodu tó ṣófo.












Leave a Reply