A kò ní owó ìtúsílẹ̀ kan tí a fẹ́ san fún àwọn agbésùnmọ̀mí fún obìnrin, ọmọdé 416 tó wà ní àhámọ́ wọn. Lónìí tíì ṣe ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹrin ọdún 2026, ní gbèdéke wákàtí méjìéláàdọ̀rin(72hrs) yóò pé tí àwọn agbésùnmọ̀mí fún ìjọba àpapọ̀ pé tí wọ́n bá dúnàdùrá lórí àwọn ọmọdé àti àwọn obìnrin tí iye wọn to ooòko-dín mẹrin lé ní irínwó 416 àwọn yóò pa gbogbo. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí ọkàn lára àwọn asoju sofin fún ìpínlẹ̀ Borno senato Ali Ndume sọ pé kò sí owó ìtúsílẹ̀ kan tí àwọn fẹ́ san fún àwọn agbésùnmọ̀mí wípé òun fara mọ́ ohun tí ìjọba àpapọ̀ sọ pé àwọn kò ní owó kọ̀ọ̀kan tí àwọn fẹ́ san fún àwọn agbésùnmọ̀mí. Àwọn Agbéṣùmọ̀mí jí àwọn ọmọdé àti àwọn obìnrin 416 náà gbé n’ilu Muoshi ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kẹta ọdún yìí, tí wọ́n sì wà ní àhámọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí láti ìgbà náà. Ali Ndume tó ń ṣojú agbègbè apá gúúsù Borno fìdí rẹ múlẹ̀ pé àwọn ọmọdé àti àwọn obìnrin tí iye rẹ̀ tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ní àwọn gbọ́ pé àwọn agbésùnmọ̀mí náà jí gbé lọ ṣùgbọ́n nígbà tó ni wọ́n tún fi ìròyìn síta pé àwọn ènìyàn 416 ni. Ó sọ pé Ó jẹ́ ohun tí ènìyàn kò le gbàgbọ́, ìyàlẹ́nu ni, ṣùgbọ́n òtítọ́ tún ni,ó ní àwọn ènìyàn tí wọ́n jí gbé yìí “àwọn ènìyàn mi ni wọ́n láti ìjọba ìbílẹ̀ mi ni wọ́n ti jí wọn gbé” ó jẹ́ ìparun pátápátá fún agbègbè náà. Ali Ndume sọ̀rọ̀ náà bí wọn ṣe n ìfòròwérò pẹ̀lú rẹ̀ lórí Arise tv. Ali Ndume ni gbogbo agbègbè náà ni òun mọ̀ dáadáa, “ó ní kó ju kìlómítà méjìlá(12-kilometer drive) sí pópónà Maiduguri – Mubi”. Nínú fọ́nrán kan tí àwọn agbésùnmọ̀mí fi síta lọ́jọ́ kọkànlélógún oṣù kẹrin ọdún 2026, ní wón ti fún ìjọba àpapọ̀ ni gbèdéke wákàtí 72 pé tí ìjọba kò bá dúnàdùrá àwọn yóò pa gbogbo àwọn ọmọdé àti àwọn obìnrin 416 tó wà ní àhámọ́ àwọn, lónìí tíì ṣe ọjọ́ ketalelogun oṣù kẹrin ọdún 2026, ní gbèdéke náà pé báyìí, ṣùgbọ́n Ali Ndume to ń ṣojú apá gúúsù Borno sọ pé kò sí owó kan tí àwọn fẹ́ san fún àwọn agbésùnmọ̀mí náà. Ó ní ṣùgbọ́n ijoba gbìyànjú gbogbo láti gba àwọn ọmọde àti àwọn obìnrin 416 tó wà ní àhámọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí náà silẹ ṣùgbọ́n kii se nípa sísan ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù náírà.
Ìjọba ní kò sí owó ìtúsílẹ̀ kan tí àwọn fẹ́ san fún àwọn agbésùnmọ̀mí fún obìnrin, ọmọdé 416 tó wà ní àhámọ́ wọn.












Leave a Reply