Àwọn agbébọn yawọ ilé ìjọsìn Christ Apostolic church Eda Oniyo ní ìpínlẹ̀ Èkìtì, wón pa Pásítọ̀ ìjọ, wọ́n jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùjọsìn gbé lọ.Ní dédé ago mẹ́jọ àbọ̀ àṣálẹ́8:30pm, ọjọ́ ìṣẹ́gun .

Àwọn agbébọn yawọ ilé ìjọsìn Christ Apostolic church Eda Oniyo ní ìpínlẹ̀ Èkìtì, wón pa Pásítọ̀ ìjọ, wọ́n jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùjọsìn gbé lọ.Ní dédé ago mẹ́jọ àbọ̀ àṣálẹ́8:30pm, ọjọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 2026, tí Pásítọ̀ àti àwọn olùjọsìn ń ṣe ìṣọ́ òru lọ́wọ́ ni àwọn agbébọn náà yawọ inú ilé ìjọsìn náà .

Àwọn agbébọn kan yawọ ilé ìjọsìn Christ Apostolic Church kan to wa ni Eda Oniyo, ní ìpínlẹ̀ Ekiti ni nnkan bi aago mẹ́jọ àbọ̀ àṣálẹ́8 :30 pm, alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun lásìkò tí wọ́n ṣe ètò ìjọsìn ìsò òru lọ́wọ́ .

Ìròyìn fi tó wa létí wípé àwọn agbésùnmọ̀mí náà pa Pásítọ̀ ìjọ náà , ti won si ji ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùjọsìn gbé lọ , bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn tí won pa ni won ti n fi idi rẹ múlẹ̀.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti fa ìjà aya ni gbogbo agbègbè náà , pẹ̀lú àwọn olùgbé náà wà nínú ìbẹ̀rù nípa àìsí ètò àbò tó péye ni gbogbo agbègbè náà. Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkìtì fidi ìkọlù náà múlẹ̀ , wọn si sọ pe iṣẹ ètò ààbò ti bẹrẹ pẹlu ìfọwọ́sowopo pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun, Àmọọ̀tẹ́kùn, àwọn fijilanti, àti àwọn ọdẹ agbègbè lati tọpa àwọn agbésùnmọ̀mí tí ó ṣe ìkọlù náà ati tú àwọn ti wọn jigbe lọ silẹ .

Àwọn alaṣẹ tun fi da aráàlú lójú pé àwọn akitiyan n lọ lọwọ láti mu àbò padabọ sipo, mu awọn oluṣewadii, ati dena ikọlu ọjọ iwaju, lakoko ti wọn rọ awọn olugbe agbègbè lati ṣọra ati jabo àwọn iṣẹ ifura, kí wọ́n ma tètè fi ọ̀rọ̀ àti àwọn ohun tó bá ń lọ ní agbègbè náà tó àwọn agbofinro létí, tí wọ́n bá rí ìrísí enikan tí ó mú ifunra lọ́wọ́ kí wọ́n pe iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti o wà ní agbègbè wọn .

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *