Àwọn ọ̀gá ọlọ́pàá ń kọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ọlọ́pàá igba (200) lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìjà àti lílo ohun-ìjà láti kojú àwọn afẹ̀míṣòfò agbésùnmọ̀mí ní Kano.
Ẹka ọlọpaa ti Ipinle Kano ti pari ikọni ti o lagbara fun oṣu kan lori ija ati lilo ohun-ija fun awọn oṣiṣẹ ọlọpaa 200; eyi jẹ apakan awọn igbiyanju lati mu agbara iṣẹ wọn pọ si ati lati mu ki iṣẹ wọn dara si ni gbogbo ipinle naa.
Awọn oṣiṣẹ naa pari ikọni wọn ni ọjọ Aje lakoko ayẹyẹ kan ti o waye ni ibudo ‘No. 9 Police Mobile Force Squadron’ ni Hotoro, Kano. Nibẹ ni Kọmiṣọna ọlọpaa, Ibrahim Bakori, ti sọ pe ikọni naa ni ero lati pese awọn oṣiṣẹ pẹlu awọn ọgbọn igbalode ti iṣẹ ọlọpaa ati awọn ilana iṣiṣẹ pataki lati koju awọn italaya aabo ti n yọju.
Bakori, ẹni ti Igbakeji Kọmiṣọna ọlọpaa ti o n dari Ẹka Isuna ati Isakoso, Audu Sabo, duro fun, sọ pe a ṣe eto naa ni ibamu pẹlu ilana lati ọdọ Inspector-General ti awọn ọlọpaa, Olatunji Rilwan Disu, lati fi pataki si imudara imọ ati agbara awọn oṣiṣẹ nigbagbogbo.O ni, “Fun oṣu kan, awọn oṣiṣẹ wa ti o to igberun meji (200) ti gba ikẹkọọ kikun lori bi wọn ṣe le mura silẹ fun ija, bi wọn ṣe le lo ohun ija, ati awọn ilana iṣe ti o yẹ fun iṣẹ ọlọpaa ni igbalode, ni awọn ibudo No. 9 PMF ni Hotoro ati No. 52 PMF ni Challawa.
“Ikọ́ni nípa lílo ohun-ìjà, àwọn ọgbọ́n ìgbésẹ̀ nígbà iṣẹ́, iṣẹ́ ọlọ́pàá tó dá lórí gbígba ìwífún tó péye, iṣẹ́ ọlọ́pàá pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ará-ìlú, bí a ṣe ń bá àwọn ènìyàn lò, àti ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn—ní ìpele tó wúlò fún iṣẹ́ gangan àti ti ìmọ̀-ìjìnlẹ̀.”Ìgbéga agbára iṣẹ́ àti ìmọ̀ kò ṣe é kà sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo; ilana títẹ̀síwájú ni. Ó gbọ́dọ̀ máa bá a lọ bí a bá fẹ́ borí nínú ogun lòdì sí ìwà-ọ̀daràn kí a sì tún lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn ènìyàn,” ni Bakori sọ.Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá rọ àwọn òṣìṣẹ́ tó ti parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà láti fi ìwà ọ̀mọ̀yàn àti ìtẹ̀lé-ìlànà hàn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ wọn, ó sì tẹnu mọ́ ọn pé àjọ ọlọ́pàá yóò máa tẹ̀síwájú láti ṣètò irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn.Ọ̀nà tí a ń gbà ṣiṣẹ́ rọrùn: kí a má ṣe àánú fún àwọn ọ̀daràn, ṣùgbọ́n kí a ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú àwọn aráàlú.
A gbọ́dọ̀ máa múra tán nígbà gbogbo láti kojú àwọn ọ̀daràn, nígbà tí a sì ń bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ-orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń tẹ̀lé òfin,” ni ó fi kún un.Ní ṣíṣáájú, Olórí Ẹ̀ka ‘No. 9 Police Mobile Force Squadron’ ní Hotoro, ACP Afeez Oyekan, sọ pé àwọn tí wọ́n kópa nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó kún rẹ́rẹ́ nípa lílo àwọn ohun-ìjà ti òde-òní, àwọn ìlànà ìbọn-títà-tó-péye, àti àwọn ọgbọ́n ìjà àti ìgbésẹ̀ oní-ọgbọ́n nígbà ìjà.
Ó sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ ọlọ́pàá náà tún gba ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, bí àwọn ọlọ́pàá ṣe lè bá àwọn aráàlú ṣe pọ̀ dáadáa, iṣẹ́ ọlọ́pàá tí ó dá lórí gbígba ìwífún àṣírí, àwọn ọgbọ́n ti òde-òní láti ṣàkóso ọ̀pọ̀ ènìyàn, iṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwùjọ, àti ìlànà àjọ ọlọ́pàá nípa lílo àwọn ètò ìbánisọ̀rọ̀ lórí ayélujára (social media).“Ọlọ́pàá tó dára gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra fún ohun-ìjà rẹ̀ nígbà gbogbo gẹ́gẹ́ bí ògbógi nínú iṣẹ́ rẹ̀, kí ó sì máa lo òye tó péye kí ó sì máa ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run,” ni Oyekan sọ.
Ó rọ àwọn òṣìṣẹ́ ọlọ́pàá náà láti lo ìmọ̀ tí wọ́n ti rí gbà nígbà ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà nípa ṣíṣe iṣẹ́ wọn pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìwà tó yẹ, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn aráàlú.Ayẹyẹ náà ní àwọn ìṣe àfihàn ọgbọ́n ìjà àti fífún àwọn tó tayọ nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ní àwọn ìwé-ẹ̀rí àti àmì-ẹ̀yẹ; àwọn wọ̀nyí ni àwọn tó ṣe dáadáa ní onírúurú ẹ̀ka, títí kan bí wọ́n ṣe ń ta ibọn, bí wọ́n ṣe ń tú ohun-ìjà ká tí wọ́n sì ń tún un kó jọ, àti bí wọ́n ṣe ṣe iṣẹ́ wọn lápapọ̀.
Lára àwọn tí ó gba àwọn àmì-ẹ̀yẹ náà ni Corporal Aminu Ahmed, Police Constable Umar Idris, Corporal Nasiru Ubale àti Police Constable Ismail Abubakar, pẹ̀lú àwọn mìíràn.












Leave a Reply