Ayode Fayose kọ̀jálẹ̀ pé ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ pé Seyi Makinde fẹ́ yọ Olubadan Ọba Abdulrasheed Adewolu Ladoja kúrò lórí ipò ọba òótọ́ ni Seyi Makinde ní ìpinnu ètò láti yọ Olubadan Ladoja.
Pẹ̀lú bí ilé ìgbìmò aṣòfin ipinle Oyo ṣe sọ pé ọ̀rọ̀ náà kò rí bẹ́ẹ̀, tí ọba Adewolu Ladoja náà sì bu ẹnu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ náà pé kò rí bẹ́ẹ̀. Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkìtì tẹ́lẹ̀ rí, Ayodele Fasoye tún fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ lórí ìkànnì ayelujara abẹ́yẹfò x rẹ̀, pé gbogbo àwọn tó bá ń ṣe iyèméjì wípé Gómìnà Seyi Makinde fẹ́ yọ Olubadan Ọba Abdulrasheed Adewolu Ladoja kúrò nípò ọba, kí wọ́n farabalẹ̀ ma tẹ̀lé ọ̀rọ̀ náà bó ṣe ń lọ, àti pé ìdí rẹ nìyẹn tí adari ilé ìgbìmò asofin oyo ṣe sọ àwọn kan dite láti yọ Seyi Makinde, ìyẹn tí fi di rẹ múlẹ̀ pé nkan ń lọ lábẹ́.
Ó tẹ̀síwájú pé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Olúbàdàn wà lára àwọn ìlànà tí wọ́n ti gbé kalẹ láti yọ ọba kúrò lórí ipò. Ó sọ pé wọ́n kọ̀jálẹ̀ wípé kò sí ááwọ̀ láàárín ọba Olúbàdàn Ladoja àti Seyi Makinde, ó ní lẹ́yìn àtéjáde tí òun gbé síta lórí ayélujára.
Sùgbọ́n báyìí wọ́n fi ẹ̀sùn kan Ọba Olúbàdàn Abdulrasheed Adewolu Ladoja pé ó ń petè pèrò láti yọ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Seyi Makinde. Bákan náà ni ó ń múra láti pé Olúbàdàn Ládọjà lẹ́jọ́. Ó sọ pé adari ilé ìgbìmò asofin ìpínlẹ̀ Gbenga Oyekola yara rẹ sọ́tọ̀ fún ẹ̀sùn bí àwọn ìgbìmò ṣe fẹ́ yọ Seyi Makinde kúrò nípò Gómìnà. Adarí ilé ìgbìmò asofin ipinle ọ̀yọ́ Gbenga Oyekola tó ń ṣojú agbègbè Atiba, sọ ọ̀rọ̀ náà lórí ìkànnì Facebook ayélujára rẹ̀ pé òun kò sí lára àwọn tó ń gbìmọ̀ láti yọ Seyi Makinde, ó tẹ̀síwájú pé òun kò ní bá wọn lọ́wọ́ sí ìdàlúrú ni ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́.Ó sọ pé “ọmọ ọkọ ni mí, mi kì í ṣe ọmọ àlè Ọ̀yọ́”.
Oníròyìn ààfin ọba Olúbàdàn Ladoja náà tún fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé kò sí ááwọ̀ kọ̀ọ̀kan láàárín ọba Ladoja àti Seyi Makinde, ó sọ òun náà ma ń ka àwọn ìròyìn tó ń jáde ṣùgbọ́n òun ò rò pé ó yẹ kí ááwọ̀ wà láàrin Olúbàdàn àti Seyi Makinde, Oníròyìn fún ààfin Olúbàdàn Ládọjà ló sọ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà ni kọmíṣọ́nà fún ìròyìn ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ Dotun oyelade náà sọ pé ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ kò tíì fi ìgbà kan sọ̀rọ̀ tàbí láti gbé irú ìgbẹ́sẹ̀ bẹ́ẹ̀.
Ó ṣàpèjúwe ẹ̀sùn náà pé kò ní ìtumọ̀.Ní báyìí gbogbo ọmọ Nàìjíríà a ti mọ̀ ẹni tí mọ ẹni tí ó yẹ kí wọ́n gbàgbọ́ pàápàá jù lọ tí ó bá ní pàtó ibi ọ̀rọ̀ náà tí ṣẹlẹ̀ tàbí wáyé, ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ kò tíì gbé irú ìgbẹ́sẹ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí ní lọ́kàn láti yọ Olubadan Ọba Abdulrasheed Adewolu Ladoja kúrò nípò ọba.










Remi Helen
Seyi makinde o fe tee