Olórí Ọlọ́dẹ àti àwọn Aṣọ́gbó márùn-ún pàdánù ẹ̀mí wọn ni Kwara bí àwọn agbesunmobi ṣe yabo wọn, tí wọ́n sì dáná sún ọkọ̀ àti ọ̀kadà wọn.

Fọ́nrán àti àwòrán tó jáde síta ṣe àfihàn bí àwọn agbesunmobi ṣe dáná sún ọkọ̀ àti ọ̀kadà àwọn Aṣọ́gbó náà, ní agbègbè níbi tí wọ́n ti ṣe ìkọlù sí wọn.

Àwọn agbesunmobi ṣe ìkọlù sí àwọn Aṣọ́gbó nílùú Nuku ijọba ìbílè Kaiama ìpínlè Kwara. Ìròyìn àti fọ́nrán tó jáde síta lórí ayélujára fìdí rẹ múlẹ̀ pé ìkọlù náà wáyé ní òru ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹ̀sán oṣù kẹrin ọdún 2026, mójú ọjọ́ ẹtì tí ṣe ọjọ́ Kẹ̀wá oṣù kẹrin ọdún 2026, ní dédé ago 3:00am,ti wọn sì pa àwọn Aṣọ́gbó márùn-ún pẹ̀lú olórí Aṣọ́gbó, tí wọn sì dáná sún ọkọ̀ àti ọ̀kadà àwọn Aṣọ́gbó náà.

Ọkàn lára àwọn olùgbé ìlú Nuku tó bá oniwe ìròyìn sọ̀rọ̀ ṣe àpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà pé ó jẹ́ ìṣòro ńlá, wàhálà ńlá tí ó sì fà ibanuje sí ọkàn ará ìlú púpọ̀. Ó ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló fara pa yánayàna, tí wọ́n sì pa àwọn Aṣọ́gbó márùn-ún pẹ̀lú olórí Aṣọ́gbó, wọn sì tún dáná sún ọkọ̀ àti ọ̀kadà àwọn Aṣọ́gbó náà .

Ó tesiwaju wípé ni ọ̀gànjọ́ òru ni àwọn agbesunmobi náà yawọ ìlú Nuku lójijì ni ìjọba ìbílẹ̀ Kaiama kwara. Ìkọlù náà wáyé ni ọ̀gànjọ́ òru ni dédé ago 3:00am lójú orun tí àwọn ará ìlú ń sún lọ́wọ́. Ó sọ wípé ó tó bí wákàtí melo kan tí àwọn agbesunmobi yìí fi ṣíṣe láabi tí kò sì sí ẹnì kankan tí ó bù wọn lọ́wọ́ rè wò, ó ní inú ìbẹ̀rù bojo ni gbogbo ara ilu wá báyìí látàrí ètò àbò tó mẹ́hẹ ni gbogbo agbègbè náà. Ẹlòmíràn tó jẹ́ olùgbé Nuku tó bá oniwe ìròyìn sọ̀rọ̀ tún fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé inú ibẹru ni gbogbo ara ilu náà wà báyìí pé àwọn agbesunmobi yìí ń gbé ìbon àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìjà olóró ni rìn kiri bí ó ṣe wù wọn ti ko si ẹni kan tí ó lé dá wọn dúró tàbí mú wọn, Ó ṣàlàyé pé ní wọn ìgbà tí àwọn agbesunmobi bá lè má pa àwọn Ọlọ́dẹ Aṣọ́gbó báyìí melomelo wa ni ara ìlú,ó ní eléyìí ló mú kí ìpayà ibẹru ifoya dé bá ara ìlú pàápàá jù lọ ìkọlù tí wọn ṣe yìí, tí àwọn agbesunmobi pa Aṣọ́gbó márùn-ún pẹ̀lú olórí Aṣọ́gbó nílùú Nuku ijọba ìbílè Kaiama ìpínlè Kwara.Tí ẹ bá ní gbàgbé irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tó wáyé ní ọjọ́ kẹta oṣù kejì ọdún 2026 yìí, níbi tí àwọn agbesunmobi tí pá àwọn ènìyàn tí ó tó igba (200) ni Kaiama kwara tí wọn sì dáná sún ilé àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Dúkìá.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *