Àwọn fulani agbésùnmọ̀mí darandaran pa olóyè Otun Balógun Oluode Okelade ni Ìbàdàn.Ọba Wahab Olabamiji ti Okelade Ibadan lo fi idi ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé àwọn Fulani darandaran pa olóyè tí ó jẹ olóyè ọtun Balogun Oluode Okelade tí orúkọ rẹ ń jé olóyè Mutairu Oladosu sínú oko tomato rẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kẹrin ọdún 2026, nílu Àsa Okelade ìjọba ìbílè ido Ìbàdàn.
Olóye Mutairu Oladosu jẹ́ ẹni Ọdún mẹ́tàdínláàdọ́ta (47).
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ nílé iṣẹ́ wa asaketvnews ni pé olóyè otun Balógun Oluode Okelade Mutairu Oladosu wà nínú oko pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ obìnrin ni àwọn Fulani darandaran da màlúù tí ó tó ọ̀ọ̀dúrún (300) wọ inú oko tomato tí olóyè kọ, wọn ṣe ìkọlù sí, wọn pa á sínú oko náà, gẹgẹ bí ohun tí Ọba Okelade ọba Wahab Olabamiji ṣe ṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà wípé ó jẹ ohun ti o ba ni lọ́kàn jẹ́ púpò, Ó ṣe àlàyé wípé bí olóògbé olóyè náà ṣe ń rìn nínú oko pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ obìnrin ni àwọn Fulani darandaran náà yawọ inú oko ti wọn si pa olóyè Balógun Oluode ti Okelade ido Ìbàdàn sínú oko tomato rẹ̀.
Ọba Wahab Olabamiji ti Okelade tesiwaju pé ọwọ tí tẹ ọ̀kan lára àwọn Fulani darandaran náà tí wọn ti fà á lé ọlọ́pàá lọ́wọ́. Ó sọ pé ìgbìyànjú lọ lórí bí wọn ṣe ma mú àwọn odaran Fulani náà.
Ọba Wahab Olabamiji Okelade ṣe àlàyé wípé ni kété tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni ṣẹlẹ̀ àwọn gba ààfin olubadan lọ láti lọ fi tó ọba olubadan Adewolu Ladoja létí pẹlu ọṣẹ́ burúkú tí àwọn Fulani ṣe fún olóye Otun Balógun Oluode Okelade bi won se pa sínú oko tomato rẹ̀.
Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ pé ní ọjọ́ ẹtì (Friday) tí ó kọjá díẹ̀ ló kù kí àwọn Fulani darandaran yìí pa olóyè otun Balogun kan yìí sínú oko tomato rẹ̀. Kini ohun tí Ọba Olubadan sọ sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà? Ọba olubadan Abdulrasheed Adewolu Ladoja pàṣẹ fún ileese olopaa ipinle Oyo pé kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kì wọn sì rí dájú pé ọwọ tẹ gbogbo àwọn odan fulani darandaran náà.
Olubadan ni òun ti gbọ pé àwọn Fulani tí pa olóyè Mutairu Oladosu sínú oko tomato rẹ̀ nílu Asa ìjọba ìbílè Ido Ìbàdàn ipinle Ọ̀yọ́. Olubadan Ladoja fi kún pé ileese olopaa ipinle Oyo tí fi dá òun lójú pé ìwádìí tí ń lọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà pé ìdájọ́ òdodo ma wáyé.
Olubadan ladoja tún tesiwaju pé Ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlè Ọ̀yọ́ ra ọwọ́ pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́, tí ó sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ pé gbogbo àwọn odaran tó bá lọ́wọ́ nínú bí wọn ṣe pa olóyè Mutairu Oladosu náà ni wọ́n yóò fi ọwọ òfin.












Olubumi
Where are ibadan warlords?
OLUBADAN 5000 vigilantes what are they doing?