Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara Abdrahman tí ṣe ìpinnu pé òun yóò san N20m fún ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà mẹta tí àwọn agbésùnmọ̀mí pa, N5milionu fún àwọn ológun mẹ́fà to fara pa ni ọgbà ológun kemanji Kwara.
Abdrahman gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara ṣe ìkéde ìpinnu yìí ni ọjọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹrin ọdún 2026, nílé ìwòsàn níbi tí Abdurrahman tí lọ ṣe àbẹ̀wò sí àwọn ológun tó fara pa yannayanna níbi tí wón ti ń gba ìwòsàn nílé ìwòsàn (Intensive care unit of the Kwara state University Teaching Hospital Ilorin) ni Abdurrahman tí ṣe ìlérí náà pé òun yóò san N20mílíọ́nù fún ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà mẹta, àti N5mílíọ̀nù fún àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà mẹ́fà tó fara pa yannayanna bí àwọn agbesunmobi ṣe kọlu ọgbà ológun kemanji Kwara. Ó sọ pé òun fi da àwọn ológun náà lójú pé wọ́n yóò rí ètò ìwòsàn tó péye.
Bákan náà ni Abdurrahman sọ pé ní òwúrọ̀ ọjọ́ ajé, ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹrin ọdún 2026, ní ìròyìn tẹ òun lọ́wọ́ pé àwọn agbésùnmọ̀mí pa àwọn ológun mẹta pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà mẹ́fà to fara pa bí àwọn agbéṣùmọ̀mí ṣe kọlu ọgbà ológun kemanji ni ijoba ibile kaiama Kwara.
Ó ní nǹkan bí ago mẹta ìdajì òwúrò kùtùkùtù a pàdánù àwọn akíkanjú ọkùnrin ológun mẹta bí Wọn ṣe ń jíjà káàdì ogun pẹ̀lú àwọn agbéṣùmọ̀mí lọ́jọ́ náà, ó ní àwọn ológun wọ̀nyí gbìyànjú láti ma jẹ́ kí àwọn agbésùnmọ̀mí pa ara ìlú àti láti máà jẹ́ wọn rí ẹnikẹ́ni jí gbé lọ.
Bákan náà ni Abdurrahman gómìnà Ìpínlẹ̀ Kwara ni òun bá àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ olóògbé àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà mẹta tí àwọn agbésùnmọ̀mí pa kẹ́dùn àwọn ológun tí wọ́n dúró ṣinṣin láti dá àbò bo ilẹ̀ baba wọn, ó ní ìpínlè Kwara àti gbogbo Nàìjíríà ni àpapọ̀ kò ní gbàgbé wọn.
Ó tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ pé òun yóò ma ṣe àtìlẹyìn fún àwọn ẹbí àti àwọn olólùfẹ́ àwọn olóògbé ọmọ Nàìjíríà mẹta náà.
Bí ẹ kò bá ní gbàgbé pé ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ni dédé ago mẹta lọ́jọ́ ajé, ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹrin ọdún 2026, ni àwọn agbesunmobi yawọ ọgbà ológun kemanji, ní ìjọba ìbílẹ̀ kaiama Kwara níbi tí wón pa àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà mẹta, tí àwọn ológun mefa sì fara pa yánnayànna.












Leave a Reply