Arábìnrin ìyá àgbàlagbà kan ẹni Àádọ́rin Ọdún Shifawu Alabi tí ó sọnu tí àwọn ẹbí ń wá ní Ọjà ọba Ìbàdàn ni aláàánú samarita kan tí bá wọn rí tí ó sì ti mú ìyà náà ẹni Àádọ́rin Ọdún lọ sí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ osun.
Ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ọ̀sun tí kéde rẹ pé ìyá àgbàlagbà kan tí orúkọ rẹ ń jẹ Shifawu Alabi ẹni Àádọ́rin Ọdún tí ó sọnu tí àwọn ẹbí rẹ tí ń ní àwọn tí rí báyìí tí ó sì tiwà nínú ọ́fíìsí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ọ̀sun .
Ọ̀gá Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ọ̀sun fìdí ìròyìn yìí múlẹ̀ ni ọjọ́ Ajé, ọjọ́ ketedinlogbon oṣù kẹrin ọdún 2026, wà nínú ọ́fíìsí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ọ̀sun. Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí ó ṣe wọn àwọn rí arábìnrin Shifawu Alabi yìí ní ọjọ́ kerinlelogun oṣù kẹrin ọdún 2026 yìí, ó fi kún ọ̀rọ̀ pé ìyá àgbàlagbà yìí tí ọkàn rẹ ti gbọgbẹ̀ láti ìgbà tí ó ti sọnù ni arábìnrin aláàánú Samarita kan láti agbègbè Tiwadayo Ofatedo mú wá sí àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn náà ni àwọn sì gba ọ̀rọ̀ lenu ìyá náà tí ìyá àgbàlagbà dárúkọ rẹ àti ọmọ bíbí ìlú rẹ pé orúkọ òun ni Shifawu Alabi, láti ọjà ọba Ìbàdàn ni òun ti wá ẹni ọdún Àádọ́rin, ṣùgbọ́n báyìí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá osun tí kéde pé Shifawu Alabi tí ó sọnu ni ọjà ọba Ìbàdàn àwọn tí rí ní ìpínlẹ̀ ọ̀sun.
Ní àkókò tí a ń kó ìròyìn yìí jọ nílé iṣẹ́ asaketvnews iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ọ̀sun kò sọ pàtó agbègbè tàbí ìlú tí àgọ́ ọlọ́pàá ti wọn ti rí Shifawu Alabi wà ni ìpínlẹ̀ Ọ̀sun.
Ọ̀gá ọlọ́pàá Abiodun Ojelabi ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ si gbogbo ènìyàn lati ṣe iranlọwọ láti lè jẹ kí Shifawu Alabi ìyá naa so pọ pẹlu awọn ìbátan rẹ̀ .
Jọ̀wọ́ pin kakiri láti rán lọ́wọ́ kí ó rí àwọn ẹbí rẹ pada pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ re,” Ojelabi fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀.












Leave a Reply