Ìjọba àpapọ̀ tí fi òfin tuntun lélẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá ní òun kii se ọmọ Nàìjíríà mọ̀ ọ́, ijọba yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní gba ìwé ìrìnà ọwọ́ wọn.
Họnọ́rébù Olubunmi Ojo mínísítà fun ọ̀rọ̀ abẹ́lé, ti páṣẹ pé kí àwọn iléeṣẹ́ tó ń rí sí ìwọlé – jáde (Nigeria Immigration Service) bẹ̀rẹ̀ sí ní máa gba ìwé ìrìnnà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Naijiria ti wọn bá ní àwọn kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà mọ́. Kí wọn sí ri dájú pé ìwé irinna wọn kò ṣíṣe fún wọn mọ́.
Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹrin ọdún 2026, ní Mínísítà fún ọ̀rọ̀ abẹ́lé Olubunmi Tunji Ojo kéde ìgbésẹ̀ tuntun yìí nínú àtéjáde kan tó ti ọwọ́ Olùgbani nímọ̀ràn ìròyìn rẹ̀, Àlàó Babatunde fi síta. Ó ṣàlàyé wípé àwọn ọmọ Naijiria ti Aare bá ti gbà pé wọ́n kìí se ọmọ Nàìjíríà mọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí kàn.
Ọmọ Nàìjíríà tí ó bá wù tó ti tó lọ́jọ́ orí, tó sì wù ú láti má ṣe jẹ́ ọmọ Nàìjíríà mọ́ ni yóò kéde rẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Tí Ààrẹ yóò sì pàṣẹ kí wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ ìkéde náà lábẹ́ òfin abala àkọ́kọ́, lẹ́yìn ìfọrúkọsílẹ̀ náà ẹni náà kò sí ní jẹ́ ọmọ Nàìjíríà mọ́,
Bákan náà ni àtéjáde náà tún ṣe àlàyé síwájú sí wípé, ẹni tí kìí se ọmọ Nàìjíríà mọ́ kò lè ní ìwé tó jẹ́ ti àṣẹ Nàìjíríà, tí ó fi mọ́ ìwé ìrìnnà Nàìjíríà. Mínísítà Olubumi Tunji Ojo ṣàlàyé wípé èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú abala òfin 29(1)àti ìkejì nínú òfin ọdún 1999. Nínú ìwé òfin Nàìjíríà. Ó sọ wípé ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ wípé òun kì í ṣe ọmọ Nàìjíríà mọ́ kò lè ní ìwé tó jẹ́ àṣẹ Nàìjíríà, títí fi mọ́ ìwé ìrìnnà Nàìjíríà. Ó tẹ̀síwàjú pé ìgbésẹ́ yìí wà láti dènà àwọn tí kìí ṣe ọmọ Nàìjíríà mọ́ láti máa fi ìwé ìrìnnà Nàìjíríà rìn ìrìn-àjò. Ó sọ pé ìjọba yóò máa ṣètò láti dá àbò bo ẹnu ibodè Nàìjíríà, láti dènà jìbìtì ìdánimọ̀, èyí tí yóò máa jẹ́ kí àwọn ènìyàn rìn ìrìn-àjò lọ̀nà tí ó tọ́, tí yóò sì tún dènà àwọn tí kò yẹ láti wọ ilé wa.
Èyí ni ohun tí ó wà nínú àtéjáde tí Olùgbani – nímọ̀ràn ìròyìn Àlàó Babatunde fun Mínísítà fun ọ̀rọ̀ abẹ́lé fi síta.
Mínísítà Olubumi Tunji Ojo ti pàṣẹ fún àwọn iléeṣẹ́ tó ń rí ìwé irinna ìwọlé- jáde pé Ki wọn maa gba ìwé irinna ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ pé òun kì í ṣe ọmọ Nàìjíríà mọ.












Leave a Reply