Ẹ yọ Bello Matawalle Nípò – Asojú sofin L’ámẹ́ríkà

Ọ̀kan lára àwọn asoju asofin Amẹ́ríkà arábìnrin Kimberly Daniel fi ẹ̀sùn kan Gómìnà Ìpínlẹ̀ Zamfara tẹ́lẹ̀ rí, Bello Matawalle pé ó ń gbìyànjú láti san owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún ọkàn lára àwọn asoju Amerika láti yìí ìpinnu UN WCD Pada lórí bí wọ́n ṣe ń pa Kìrìstẹ́nì nínú Naijiria.

Arabirin Kimberly Daniel sọ̀rọ̀ yìí nínú fọ́nrán kan tó fi léde ni ọjọ́ ìṣẹ́gun ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹrin ọdún 2026, Ó sọ pé kí ìjọba Nàìjíríà yọ MATAWALLE nípò, ọkàn lára àwọn asoju sofin Amẹ́ríkà fi ẹ̀sùn kan Gómìnà Ìpínlẹ̀ Zamfara tẹ́lẹ̀ rí, Bello MATAWALLE pé ó gbìyànjú láti san owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún ọkàn lára àwọn asoju Amerika láti yìí ìpinnu UN WCD Pada lórí ipaniyan pàápàá yóò ju lọ bí àwọn agbésùnmọ̀mí ṣe ń pa Kìrìstẹ́nì nínú Nàìjíríà.

Arabinrin Kimberly Daniel to soju Ẹkùn gbogbo agbègbè Florida Amerika fi kún ọ̀rọ̀ rẹ pé ọkàn lára àwọn asoju Amerika tí wón dibo yàn LÁMẸ́RÍKÀ lábẹ́ ìṣèjọba trump ni Bello MATAWALLE ń fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ láti yìí ipaniyan bí wọ́n ṣe pa àwọn Kìrìstẹ́nì nínú Naijiria padà pé, ní ilé iléeṣẹ́ ìròyìn asaketvnews sì fidi ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ látàrí fọ́nrán tí Arábìnrin kimberley Daniels FI síta lórí ayélujára níbi tí ó ti sọ̀rọ̀ náà, ó fi kún ọ̀rọ̀ pé kí ìjọba Nàìjíríà Aare Bola Ahmed Tinubu yọ Bello MATAWALLE kúrò nípò mínísítà fún ètò àbò fún ìpínlẹ̀ zamfara, Kimberly tún ẹ̀sùn kan wípé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ipaniyan tó ń ṣẹlẹ̀ ni gbogbo àgbègbè ìpínlẹ̀ wọ̀nyí ọwọ Bello MATAWALLE kò mọ nínú rẹ, àwọn ìpínlẹ̀ bí :plateau, Benue, Kaduna, àti àwọn ìpínlẹ̀ mìíràn nínú Nàìjíríà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *