Àtẹ̀jáde kan tí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ekiti tẹ́lẹ̀ rí, Ayodele Fayose fi sí orí ìkànnì ayélujára abẹ́yẹfò x rẹ, lo tí sọ pé òun gbọ́ wípé Seyi Makinde ń pète pèrò láti yọ Olubadan Ọba Abdulrasheed Adewolu Ladoja kúrò lórí ìtẹ́ ipò ọba olubadan.
Lónìí tíì ṣe ọjọ́ àìkú ọjọ́ Kejìlá, oṣù kẹrin ọdún 2026, ni gómìnà ìpínlè Èkìtì tẹ́lẹ̀ rí,
Peter Ayodele Fayose kọ ọ́ jáde lórí òpó x rẹ̀ pé:
Mo gbọ́ dájúdájú wípé Gómìnà ìpínlẹ̀ Òyọ́ Seyi Makinde n pète pèrò láti yọ Olubadan tí ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Abdulrasheed Adewolu Ladoja lórí ìté ipò olubadan.
Ọ̀sẹ̀ yìí ni Seyi Makinde fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ète náà, pẹ̀lú fífún olubadan ní ìwé ẹ̀sùn, bí olubadan kò ṣe yọjú síbi ayẹyẹ igbade àwọn olóyè gíga mẹ́ta tilẹ̀ ibadan tí wọn ṣe ni ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn báyìí, pẹ̀lú àwọn ẹ̀sùn mìíràn tí Seyi Makinde kà sí Olubadan lẹ́sẹ̀.
“A ó ma wò ní tiwa ni , tí ṣìgìdì Seyi Makinde tó bá fẹ́ ṣeré ẹ̀tẹ́.. “Èyí ni ohun tí Ayodele Fayose kọ sórí ìkànnì ayélujára abẹ́yẹfò x rẹ̀.
Ó ń rúgbó ń bọ̀! Ẹ̀yin ènìyàn kini ohun tí ẹ bá wa rí sọ sí ohùn tí Ayodele Fayose sọ yìí?












Monday
You are the best