Trump ti dí ojú ọ̀nà tí orílẹ̀ èdè Iran lè gbà gbé epo rọ̀bì kọjá sí àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn , bákan náà ni ó tún dí ibi tí Iran lè gbà gbé ọkọ ojú omi wọlé.

Ní alẹ́ ọjọ́ àìkú tíì ṣe ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹrin ọdún 2026, ni iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà tún kéde wípé ìgbẹ́sẹ̀ Amẹ́ríkà náà máa dènà àwọn ọkọ̀ láti gbé epo rọ̀bì wọ orílẹ̀ èdè Iran jáde nibẹ.

Amẹ́ríkà ni àwọn kò ní gbà kí ọkọ̀ ojú omi Iran gbé epo jáde ní orílẹ̀ èdè náà, tí wọ́n kò bá ṣí oju ọ̀nà tí gbogbo àgbáyé ń gbé epo rọ̀bí gbà kọjá – strait Hormuz. Trump kọ sí ojú òpó Truth social rẹ pé ìjọba máa fi àwọn ológun ojú omi máa di Orílẹ̀ èdè Iran pa. Láti máa jẹ ki iran rí ibi gbé epo rọ̀bí gbà kọjá mọ́. Trump ti di ojú ọ̀nà tí iran lè gbà gbé epo rọ̀bí kọjá sí àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n jọ ń doko òwò, bákan náà ni wọn tún di ibi tí Iran lè gba gbé ọkọ ojú omi wọlé tí wọn lè tí máa ta epo rọ̀bí fún àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn.

Aṣòfin Mike Turner ti Ohio sọ pé dídí ọ̀nà mọ́ Iran máa mú kí ìfẹnukò wáyé lórí Strait of HormuzSẹ́nétọ̀ Mark Wagner ti Virginia sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn CNN pé òun kò mọ bí dídí ọ̀nà mọ́ Iran ṣe máa mú àwọn aláṣẹ Iran láti ṣí Strait of Hormuz.

Àmọ́ aṣòfin Mike Turner ti Ohio sọ pé dídí ọ̀nà náà máa jẹ́ ìgbésẹ̀ láti mú kí ìfẹnukò wáyé lórí Strait of Hormuz.Ó ní ọ̀rọ̀ tí Trump sọ nípa pé àwọn kò ní jẹ́ kí Iran jẹ́ alákòso tó ń ṣàmójútó àwọn tó ń gba ọ̀nà náà kọjá túmọ̀ sí pé, ó ń pe àwọn alábàáṣepọ̀ Amẹ́ríkà láti dá sí ọ̀rọ̀ náà nítorí ó nílò àmójútó.Ṣáájú kí Amẹ́ríkà àti Iran tó fẹnukò láti dáwọ́ ogun dúró fún ìgbà kan ná, Trump ni ó sọ pé òun máa ṣe ìkọlù sáwọn ohun amáyédẹ̀rùn Iran.Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn, pàápàá àwọn ara Amẹ́ríkà, ló gbàgbọ́ pé ìdí tí Amẹ́ríkà fi ń gbógunti Iran, tó fi mọ́ ṣíṣí Strait of Hormuz, fífún àwọn èèyàn Iran ní àǹfààní láti gbé ìgbé ayé tó wù wọ́n àti fífi òpin sí ṣíṣe àdó olóró nuclear weapon ni kò wá sí ìmúṣẹ.

Lẹ́yìn ìjíròrò láàárín Amẹ́ríkà àti Iran forí sánpọ́n ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump ti kéde ìgbésẹ̀ míì láti fi wá ojútùú sí àwọn ọ̀nà tí ogun fi máa parí.Trump, nínú àtẹ̀jáde tó fi sórí ìkànnì Truth Social rẹ̀ sọ pé ìjọba máa fi àwọn ológun ojú omi máa di Iran pa.Amẹ́ríkà ní àwọn kò ní gbà kí ọkọ̀ ojú omi Iran gbé epo jáde ní orílẹ̀ èdè náà, tí wọ́n kò bá ṣí Strait of Hormuz.Ó kọ sójú òpó náà pé ” kò sí ẹni tó máa ọ̀nà tí kò bá òfin mú tó máa gba orí omi láì farapa.Ó ní Amẹ́ríkà máa bẹ̀rẹ̀ sí ní wà kùsà ní Strait of Hormuz láti ri dájú pé gbogbo àwọn ọkọ̀ ojú omi tó ní ìbáṣe pẹ̀lú Amẹ́ríkà rí ọ̀nà náà gbà kọjá.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *