Ọmọ Nàìjíríà tó wà ní UK, Adewale Anthony Sobogun ẹni ọdún (61yrs)rí ẹ̀wọ̀n ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n(28yrs ) he, fún ẹ̀sùn ìfipábá ọmọdébìnrin méjì lò pọ̀.

Adewale Sobogun jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta, tí ó sì ti ń gbé orílẹ̀ èdè Biritiko( Uk) ti pẹ́.

Ilé ẹjọ́ Inner London Crown ju Adewale Sobogun Anthony sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n (28yrs) fún ẹ̀sùn ìfipábá ọmọdébìnrin méjì lò pọ̀, tí wọ́n sì ti fi ẹ̀sùn kan náà láti nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (15)sẹ́yìn, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ọdún 2026 ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Uk fidi ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé ilé ẹjọ́ Inner London Crown ti gbé ìdájọ́ náà kalẹ tí wọ́n sì fún Adewale Anthony Sobogun ní ẹ̀wọ̀n ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n (28).

Látàrí bí wọ́n ṣe ní ó jẹ̀bi ẹ̀sùn ẹ̀ṣẹ̀ ìlòkúlò ìbálòpọ̀ ti kii ṣe aipẹ mẹ́tàdínlógún tí wọn fi kan – an.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá UK tí ṣe àkíyèsí tí ìwádìí sì fi múlẹ̀ pé Adewale Anthony Sobogun bá ọmọdébìnrin méjì lò pọ̀ tí ọjọ́ orí ọkàn nínú àwọn ọmọ náà jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá (13),tí ọjọ́ orí èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún márùndílógún (15),ti àwọn ọmọbìnrin náà sì jẹ́ àwọn tí wọ́n bí ní nǹkan bí ìbẹ̀rẹ̀ 1990s sí ìbẹ̀rẹ̀ 2000s.

Ọ̀kan nínú àwọn ọmọdébìnrin náà sọ pé Sobogun tí bá oyún jẹ́ fún òun.

Bí àwọn ọlọ́pàá se gbó èyí, wọn tọ ilé ìwòsàn náà lọ láti lọ wo àkọsílẹ̀, nígbà tí wọ́n de ibẹ̀ wọn rí wípé lóòótọ́ ni ti àkọsílẹ̀ sì gbé gbogbo rẹ jáde nílé ìwòsàn.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá UK, fi ọwọ òfin mú Sobogun ni ọjọ́ kejì oṣù keje ọdún 2025, lẹ́yìn náà ni wọ́n fi ẹ̀sùn kan an tí ó sì jebi àwọn ẹ̀sùn náà látàrí ìwádìí tí àwọn ọlọ́pàá ṣe. ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Charlotte sàlàyé pé àwọn ọmọbìnrin méjèèjì ló jẹ́ kí àwọn rí idajọ òdodo ọ̀rọ̀ náà ṣe nítorí wípé wọn jẹ́ ẹni tí ó ní ìgboyà tí kò bẹ̀rù láti sọ ìṣẹ̀lẹ̀ ìfipábánilòpò tó ṣẹlẹ̀ sí wọn.

Ó wá rọ gbogbo àwọn ènìyàn pé tí wón bá ní irú ipenija báyìí kí wọn sọ̀rọ̀ síta, kí wọn ma bẹ̀rù wípé kò sí bí ìṣẹ̀lẹ̀ ìfipábánilòpò náà ṣe lè rí burú tó tàbí pẹ́ tó ìdájọ́ òdodo máa wáyé. Ó tún ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú, àdúgbò pàápàá jù lọ nínú ẹbí ni àwọn irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tíì ṣẹlẹ̀ ṣùgbọ́n ìbẹ̀rù tàbí ìtìjú ni kí í jẹ ki àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ síta.

ó rọ àwọn ènìyàn pé kí wọ́n ma gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ síta tí wọ́n bá ní irú ìpèníjá ìfipábánilòpò yìí,Ó fi kún ọ̀rọ̀ pé tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ síta ni wọn a lè rí ìdájọ́ òdodo gbà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *