Àwọn agbébọn pa Dasola Sanusi òṣìṣẹ́birin ẹlẹ́ṣọ àbò “ManO war” ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Àwọn afurasí agbébọn ajinigbe tí pa òṣìṣẹ́birin ẹlẹ́ṣọ Dasola Sanusi, ẹlẹ́ṣọ àbò “ManO war”.
Bí wọn ṣe ṣe ìkọlù sí àwọn arìnrìn-àjò ni pópónà Ìbàdàn si Ago-Iwoye ọ̀nà tó wà láàárín ìpínlẹ̀ Ogun àti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí ó tẹ wá lọ́wọ́ nílé isẹ wa asaketvnews ni pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ ni ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹrin ọdún 2026, gẹgẹ bí ohun tí àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ lójú wọn ṣe ṣàlàyé pé ní nkan bí ìrọ̀lẹ́ ni dédé ago mẹ́fà àbọ̀6:30 pm ọjọ́ abameta tíì ṣe ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹrin ọdún 2026, bí àwọn ẹlẹ́ṣọ àbò ṣe ń padà lọ sí ọ́fíìsí wọn lọ́nà pópónà Ibadan – ago iwoye ni àwọn agbébọn da ìbọn bole fun ọkọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣọ àbò náà. Ó fi kún ọ̀rọ̀ pé àwọn ẹlẹ́ṣọ àbò kan sá àsálà fún ẹ̀mí wọn tí àwọn mìíràn nínú wọn sì fara pa yánnayànna nínú ìkọlù náà. Ó ní sáré doola ẹ̀mí àwọn ẹlẹ́ṣọ àbò tó fara pa yannayanna lọ sí ilé ìwòsàn tó wà ní ago iwoye fún ìwòsàn to péye. Ó ní kété tí wọ́n kọjá CRIN ọkọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣọ àbò ManO war àti àwọn arìnrìn-àjò ni àwọn agbébọn náà yọ sí wọn lójijì tí wón sì da ìbọn bole fún wọn. Ó ṣàlàyé pé ní kété bí wọ́n ṣe ń kó àwọn ẹlẹ́ṣọ àbò tó fara pa yannayanna dé ilé ìwòsàn ago iwoye ni Dasola Sanusi jáde láyé, ṣùgbọ́n tí ẹlẹ́ṣọ àbò tí orúkọ ń jẹ Emmanuel ń gba ìwòsàn lọ́wọ́, ó ní àwọn ẹlẹ́ṣọ àbò obìnrin méjì ń gba ìwòsàn nibẹ náà. Ó ní Dasola Sanusi ẹlẹ́ṣọ àbò obìnrin tó kú nínú ìkọlù ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ibanuje àti ọgbẹ́ ọkàn fún àwọn ẹlẹ́ṣọ àbò “ManOwar”. Ẹni tí ó jẹ agbẹnusọ fún iléeṣẹ́ ẹlẹ́ṣọ àbò ManOwar Ibrahim Bello lo kéde rẹ pé Dasola Sanusi ẹlẹ́ṣọ àbò náà tí jáde láyé o sì tún ṣàlàyé pé ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ láàárín òpópónà ọ̀yọ́ sí ogun. Bákan náà ni Ayanlade agbenusọ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ fi di ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ látàrí ìpè to gbà lórí èrò ibanisoro rẹ̀ láti owó oniroyin fún àwọn ẹlẹ́ṣọ àbò ManO war ni ọjọ́ ìṣẹ́gun. Ayanlade ni ó ṣe é ṣe kó jẹ́ pé àwọn ajinigbe ni àwọn tó ṣe ìkọlù náà, ó sọ alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ náà sọ pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù yìí wáyé lai pé seyin níbi tí wọ́n ti ṣe ìkọlù láti jí àwọn awako ari èrò inú ọkọ̀ gbé ṣùgbọ́n nígbà tí ìròyìn tẹ àwọn lọ́wọ́ lójú ẹsẹ ni àwọn kò awon eléso abo lọ láti lọ doola èmi wọn lọ́wọ́ àwọn ajinigbe náà gbogbo awon èniyàn tó fara pa ni àwọn kò ló sì ilé ìwòsàn tó wà ní tòsí láti Awa-Ijebu tí pẹ̀lú ọkọ̀ kan tí ó ti bàjẹ́, tí àwọn sì fi tó DPO Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun létí.












Leave a Reply