Àwọn jàǹdùkú lẹ́yìn olóṣèlú na alága ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀wọ̀, wọ́n na à nà já létí, wọ́n na gba Sokoto nìdí rẹ̀.

Bí àwọn jàǹdùkú lẹ́yìn olóṣèlú ṣe yinbon sókè gbogbo ará ìlú ń sá kiri,ti gbogbo agbègbè náà sì dabi tí pé ojú ogun ni àwọn ará ìlú wà Ìbẹ̀rùbojo dé bá àwọn òṣìṣẹ́ nínú òfin ijoba ìbílè ni ọ̀wọ̀ ni ìpínlẹ̀ Ondo ni ọjọ́ ajé, ogunjo oṣù kẹrin ọdún 2026, bí àwọn jàǹdùkú ṣe YAWỌ òfin , da ìbọn bolẹ̀ nínú ọgbà ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀wọ̀, wọ́n na alága ìjọba ìbílẹ̀ ọ̀gbẹ́ni Tope Omolayo , wọn bọ́ Sokoto ìdí rẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ojú rẹ sọ pé wàhálà ńlá bé sílè, rògbòdìyàn ńlá ṣẹlẹ̀ láàárín ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC sí ọmọ ẹgbẹ́ APC ìlú Ọ̀wọ̀ kan náà, ó ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC náà ló gbógun ti ara wọn látàrí ipò Kànsẹ́lọ̀ tí wón ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn.Àwọn ará ìlú tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ lójú wọn sọ pé alága ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀wọ̀ tí àwọn jàǹdùkú lẹ́yìn olóṣèlú na yìí fẹ́ wọlé sínú òfin rẹ fún ọjọ́ àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí wọ́n jáwé gbélé rẹ fún un, fún oṣù mẹ́fà, ní ọjọ́ ajé, ogúnjọ́ oṣù kẹrin ọdún 2026, bí alága ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀wọ̀ ṣe fẹ́ wó inú òfin rẹ ni àwọn jàǹdùkú lẹ́yìn olóṣèlú náà yawọ inú ọgbà ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n sì na alága ja pátá mọ ọ nìdí. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí tí a ṣe lórí ìṣẹ̀lẹ̀ nílé iṣẹ́ wa asaketvnews ni pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ olóṣèlú APC náà ló na alága ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀wọ̀ tí òun sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ APC. Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀ lójú ti wọn fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ṣàlàyé tí wọ́n sì dárúkọ pé àwọn ọmọ ìlú Ọ̀wọ̀ to jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ APC náà ló na alága ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀wọ̀ tó jẹ́ APC, Èyí ni orúkọ àwọn afurasí jàǹdùkú tí wón dárúkọ pé wọ́n na alága ìjọba ìbílẹ̀ ẹgbẹ́ APC Ọ̀wọ̀ :Kunle Odide to jẹ́ àbúrò Kọmíṣọ́nà fún ètò isuna owó ìpínlẹ̀ Ondo ,orúkọ àwọn tó kú ni :Eko, Gentle, Jentle, Festus, Akeem, Goldberg àti Lastangle. àwọn kan tún fi kún pé láti inú ààfin ọba ọlọ́wọ́ ni àwọn jàǹdùkú náà tí wá ti wọn si yawọ inú ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n ti na alága ìjọba ìbílẹ̀ náà. àwọn ni inú bẹru bojo ni àwọn wà pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n ní ogun àti wàhálà ńlá ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ fún gbogbo agbègbè ìlú Ọ̀wọ̀. Àwọn ará ìlú , àti gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀wọ̀ ké gbàjarè fún Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ondo Ayedatiwa pé kí ó da sí ọ̀rọ̀ àti ètò àbò tó mẹ́hẹ ni gbogbo agbègbè ìlú Ọ̀wọ̀ ìpínlẹ̀ Ondo. Ṣùgbọ́n ní àkókò tí a fi kó ìròyìn yìí jọ nílé iṣẹ́ asaketvnews agbenusọ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo Jmoh Abayomi ni àwọn tí kò àwọn ọlọ́pàá lọ sí ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀wọ̀ láti lọ yanjú rògbòdìyàn tó ṣẹlẹ̀ níbè àti láti pèsè àbò sórí àwọn òṣìṣẹ́ ijoba ìbílè Ọ̀wọ̀ àti àwọn ènìyàn inú ìlú náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *