Ìjọba àpapọ̀ tí kó gbogbo orúkọ àwọn ọmọ Nàìjíríà síta ,lára wọn ni Tukur Mamu, Simon Njoku Ekpa,tí ó jẹ adari IPOB tí ìjọba orílẹ̀ èdè Finland mú ní ọdún 2024 tí wọn sì fi ẹ̀sùn ìwà ìgbésùnmọ́mí kàn – án látàrí bí ó ṣe ń pè fún idasile òmìnira Biafra àti àwọn gúrúpù12 mìíràn, tó ń ṣe ìrànlọ́wọ́ àti àtìlẹyìn fún àwọn agbésùnmọ̀mí.
Àkójọpọ̀ orúkọ àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ìjọba àpapọ̀ kò síta lórí ìkànnì ayélujára Nigeria Sanctions Committee (NIGSAC), ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ iye ọmọ Nàìjíríà àti ipa tí wọn ń kó bí wọ́n ṣe ńṣe àtìlẹyìn fún àwọn agbésùnmọ̀mí. Ìjọba Nàìjíríà tí fi orúkọ àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan tí ó tó méjìdínláàdọ̀ta (48) ati àwọn iléeṣẹ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ 12, tí ìjọba fi ẹ̀sùn kan wọn wípé àwọn ló ń ṣe ìrànlọ́wọ́ owó àti àtìlẹyìn fún àwọn agbésùnmọ̀mí inú Nàìjíríà. Pẹ̀lú bí gbogbo nkan ṣe ń lọ tí ọ̀rọ̀ ètò àbò lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà mẹ́hẹ, ìjọba ni àwọn fẹ́ wá gbogbo ọ̀nà láti dènà àwọn tó ń gbé owó sílẹ̀ fún àwọn agbésùnmọ̀mí.
Àwọn ìgbìmọ̀ ìjẹniníyà Naijiria lábẹ́ aláṣẹ ti ọ́fíìsí tí olùdámọ̀ràn fún ètò àbò Nàìjíríà ni pẹ̀lú ipò ìdojúkọ àwọn iṣẹ́ ìlànà ètò àbò tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni ló jẹ́ kí ìjọba kó orúkọ àwọn alátìlẹyìn àwọn agbesunmobi síta, pàápàá jù lọ àwọn tó ṣe ìrànlọ́wọ́ owó fún àwọn olùmoòye wọn, nkan ìjà ogún ti wọn n lò àti àwọn àjèjì alámọrí. BÍ ó ti lè jẹ́ pé orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà àti àjọ àgbáyé(UN) tí fi ìgbà kan gbé orúkọ àwọn kan síta , Ṣùgbọ́n báyìí ìjọba àpapọ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà náà tí wá fi orúkọ àwọn ọmọ Nàìjíríà tuntun mìíràn síta tí wọn fi ẹ̀sùn kan wípé wọn ṣe àtìlẹyìn owó fún àwọn agbésùnmọ̀mí.
Èyí ní àwọn orúkọ tí ìjọba Nàìjíríà fi síta o:
Abdulsamat Ohida, Mohammed Sani, Abdurrahman Abdurrahman, Fatima Ishaq, Tukur Mamu Yusuf, Ghazali Muhammad,, Sallamudeen Hassan, Adamu Ishak, Hassan Isah, Abdulkarim Musa, Umar Abdullahi, Abdurrahman ÀDÓ, Bashir Yusuf, Ibrahim Alhassan, Muhammad Isah, Salihu Adamu, and Surajo Mohammed.
Àwọn orúkọ mìíràn rèé :
níbi ni àwọn orúkọ adarí IPOB àti àwọn ọmọ ibo kọ̀ọ̀kan tí ìjọba fi ẹ̀sùn kàn wà:
Fannami Bukar, Muhammed Musa, Sahabi Ismail, Mohammed Buba, Jama’atu Wal-Jihad, Ansarul Sudan (ANSARU), Islamic State West Africa Province (ISWAP), Indigenous People of Biafra (IPOB), Yan Group, Yan Group NLBDG, Adamu Hassan, Hassan Mohammed, Usman Abubakar, Kubara Salawu, Rabiu Suleiman, Simon Njoku, Godstime Iyare, Francis Mmadubuchi, John Onwumere, Chikwuka Eze, Edwin Chukwuedo, Chiwendu Owoh, Ginika Orji, Awo Uchechukwu, Mercy Ali, Ohagwu Juliana, Eze Okpoto, Nwaobi Chimezie, and Ogumu Kewe.
Orúkọ àwọn iléeṣẹ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ to n se àtìlẹyìn fún àwọn agbésùnmọ̀mí rèé :
West and East Africa General Trading Co. Ltd, Settings Bureau De Change Ltd, G. Side General Enterprises, Desert Exchange Ventures Limited, Eagle Square General TradingCo. Ltd, Alfa Exchange BDC, Alin Yar Yaya General Enterprises, K. Are Nigeria Limited, Suhailah Bashir General Enterprises, Igwe Ka Ala Enterprises, Seficuvi Global Company, and Lakurawa Sect.Ní àìpẹ́ yìí ni ìjọba Amerika gbé orúkọ àwọn ènìyàn kan síta tí wọ́n sì ni wọn ti gbẹ́ṣẹ̀ lé àwọn dúkìá nkan ìní wọn àti pé ìwé ìrìnna wọn kò lè wọlé sí Amerika.
Bí ẹ bá ní gbàgbé nínú oṣù Kejìlá ọdún 2025 ìwé ìròyìn gbé orúkọ àwọn 23 kan síta àwọn ọmọ Nàìjíríà ogún (20)ti àwọn òyìnbó ọmọ ilẹ̀ òkèèrè jẹ́ mẹ́ta (3) ti fi ẹ̀sùn kan wọn pé àwọn ló ń ṣe olugbowo,ìrànlọ́wọ́ owó alátìlẹyìn fun awon agbésùnmọ̀mí Bokoharam nínú Nàìjíríà. Àwọn orúkọ náà ni wọn yìí Alhaji Saidu Ahmed, Usaini Adamu, Muhammad Sani Adam, Abubakar Adamu Yellow, Murtala Abdullahi Jega, Sadiq Garba Abubakar, Hussaini Adamu, Mustapha Ibrahim Yakubu, Ali Abdullahi Yusuf, Nasiru Shuaibu, Yusuf Ghazali, Mansur Muhammad Usman, Yazid Usman Muhammad, Alhaji Musa Emma, Modu Sulum, Adamu Aliyu Kanoma, Habibu Muhammad Usama, Nurudeen Gani Aliyu, Ladan Ibrahim, Awon àjèjì tí wọ́n fi ẹ̀sùn kan :international suspects Tribert Rujugiro Ayabatwa, Paul Nkwaya, and Aboubacar Hima.
Bákan náà bí ẹ bá ní gbàgbé nínú ọdún 2022 ni ijoba mú arákùnrin tí orúkọ rẹ ń jẹ Tukur Mamu tí ó jẹ oniwe ìròyìn, ó sì jé ọmọ bíbí ìlú Fika ni ìpínlè Yobe tí ìjọba fi ẹ̀sùn kan pé ó ń ṣe agbenuso, iranlowo owó àti bí ó ṣe ń bá àwọn agbésùnmọ̀mí dúnàdùrá, orúkọ arákùnrin náà tún wà lára àwọn orúkọ mìíràn tí ìjọba àpapọ̀ fi síta báyìí.












Leave a Reply