Ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà tí kó àwọn ọmọ ogun igba (200) ránṣẹ́ lọ sí Turkey láti lọ kọ́ ìjà ogun jíjà láti kojú àwọn agbésùnmọ̀mí.
Lónìí tó jẹ́ ọjọ́ àìkú tíì ṣe ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹrin ọdún 2026, ni Ọ̀gágun Musa Christopher tó jẹ́ mínísítà fún ọ̀rọ̀ ètò àbò fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (CDS) ló fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé ìjọba tí rán àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà igba (200) lọ sí Turkey láti lọ kọ́ bí wọn ṣe jagun láti lè wá koju àwọn agbésùnmọ̀mí afẹ̀míṣòfò inú Nàìjíríà .
Bí ẹ kò bá ní gbàgbé ni ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí ni Ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kìíní ọdún 2026, ni Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà Bola Ahmed Tinubu lọ sí orílè èdè Turkey, tí ó sì ti ọwọ bọ ìwé àdéhùn ifowosowopo idokoowo tí iye owó rẹ tó $1bilionu láàárín Turkey àti Nàìjíríà. Ohun tí ó sì wà nínú ìwé náà ni pé orílè èdè Turkey ni àwọn má bá Nàìjíríà dojú ìjà kọ àwọn agbésùnmọ̀mí inú Nàìjíríà. Bákan náà ni wọn tun tọ́wọ bọ ìwé àdéhùn ìdókoòwò tí iye rẹ jẹ́ mẹsan (9) ti owo rẹ tó $1bilionu àwọn ohun tí orílè èdè Turkey àti Naijiria jọ fẹ́ ṣe papọ̀, láàárín Nàìjíríà àti Turkey pé Naijiria a má kó epo rọ̀bì fún wọn ti Orilẹ̀ èdè Turkey náà ni àwọn àwọn yóò ma kó ọkọ òfuurufú baalu, irinse ogun àti àwọn rọ́bà wọlé sí Nàìjíríà, àti àwọn nkan mìíràn .
Ṣùgbọ́n báyìí ìṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ lórí àdéhùn tí wọn jọ ṣe, ìjọba Nàìjíríà tí kó ọmọ 200 ránṣẹ́ sí orílè èdè Turkey láti lọ kọ́ bí wọ́n ṣe ń jagun.












Leave a Reply