Nítorí ọ̀rọ̀ ìdìbò2027 tó ń bọ̀ lọ́nà ni ó fa àìsí ètò àbò tó ń peléke si, tí ìdìbò bá ti parí,ẹ kò ní gbúrò àdó olóró mọ́.

Nítorí ọ̀rọ̀ ìdìbò2027 tó ń bọ̀ lọ́nà ni ó fa
àìsí ètò àbò tó ń peléke si, tí ètò idibò bá ti parí, ẹ kò ní gbúrò àdó olóró Mó

Ààrẹ ilé ìgbìmò aṣòfin àgbà Godwin Akpabio ló sọ ọ̀rọ̀ náà níbi tí wọ́n ti ṣe ifilọ́lẹ̀ ilé NRS ni Abuja tí í ṣe Olú ìlú Nàìjíríà,

Ó ṣàlàyé pé ètò ìdìbò ọdún 2027 tó ń bọ̀ lọ́nà ni ó fa àìsí ètò àbò tó ń peléke si, tí ètò idibo bá ti parí, ẹ kò ní gbúrò àdó olóró kan ṣoṣo mọ́.

Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ pé ní kété tí wọ́n bá dibo tán to pé ọ̀sẹ̀ méjì ìkọlù àti àdó olóró tí àwọn agbesunmobi ń ju kakiri inú ìlú yóò dópin.

Akpabio sọ pé àwọn ọmọ Nàìjíríà dúró digbi sẹ́yìn Aarẹ Tinubu pé wọn yóò sì dibo fún un, pẹ̀lú bí ó ṣe ṣàpèjúwe àìsí ètò àbò inú ìlú.

Ó sọ pé ṣe ẹ rí bí àìsí ètò àbò ṣe ń peléke si lónìí , nítorí ètò idibò tó ń bọ̀ lọ́nà ni, ó fi kún ọ̀rọ̀ pé àwọn ènìyàn kan ló finúfídọ̀ ń lò àwọn agbesunmobi láti bá ìṣèjọba Tinubu jẹ́. Akpabio gbóyà sọ pé ọ̀rọ̀ àìsí ètò àbò inú ìlú yóò dúró ní kété tí ìdìbò bá parí, ó sọ fún ara ilu kí wọ́n ma wò’ran pé ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìdìbò won Kò ní gbúrò àdó olóró tàbí ijinigbe mọ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *