Àwọn Agbéṣùmọ̀mí da ìbọn bolẹ̀ yawọ ọgbà àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà tó wà ní kemanji ni ijoba ìbílẹ̀ kaiama Kwara, wọn pa ológun mẹrin tí wón sì tún jí ọ̀pọ̀ àwọn ará ìlú kemanji gbé lọ.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn olùgbé agbègbè náà tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ṣe sọ pé ìkọlù náà wáyé ní àárọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ ajé, tíì ṣe ogúnjọ́ oṣù kẹrin ọdún 2026, ní àwọn agbésùnmọ̀mí yawọ ọgbà ológun Nàìjíríà tó wà ní kemanji ní ìjọba ìbílẹ̀ kaiama kwara nibí tí wọn tí pa àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà mẹrin tí wón sì jí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn gbé lọ, ó tẹ̀síwájú pé ìkọlù náà bá àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà lójijì nítorí pé ní àárọ̀ kùtùkùtù tí ìkọlù náà ṣẹlẹ̀ ojú ooru ni ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà wà, ó ní ojú ooru tí àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà wà kò jẹ́ kí ọwọ wọn ká àwọn agbésùnmọ̀mí náà. Ó ṣàlàyé pé ẹnu ibodè tó sún mọ́ etí igbó kìjikìji ni ìlú kemanji tí ọgbà ológun yìí níbi tí àwọn agbesunmobi tí ṣe ìkọlù náà wà.
Ó ní àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà tó wà nínú ọgbà ológun náà ń sún lọ́wọ́ nígbà tí àwọn agbésùnmọ̀mí ya bo wọn ní nkan bí ago mẹ́ta ìdajì òwúrò kùtùkùtù, tí àwọn agbésùnmọ̀mí sì pa àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà mẹta jí ọ̀pọ̀ àwọn ará ìlú náà gbé lọ.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí ọkan lára àwọn olùgbé agbègbè náà ṣe tí o sì fidi ìkọlù náà múlẹ̀ títí di àkókò tí a fi kó ìròyìn yìí jọ nílé iṣẹ́ asaketvnews ó ní àwọn kò ti gbúrò àwọn ènìyàn wọn tí àwọn agbésùnmọ̀mí jí gbé lọ.












Leave a Reply