Awọn Agbéṣùmọ̀mí ti ji ọ̀gá àgbà ilé ìwé ,àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé lọ nilu Ahoro-Esinele ní ìjọba ìbílẹ̀ Oriire ìpínlẹ̀ Ọyọ ni ọjọ́ kẹẹ̀dógún Oṣu Karun , Ọdun 2026 ní dédé ago mẹ́jọ sí ago mẹ́sàn àárọ̀ ọjọ́ Ẹtì . Àwọn agbébọn ti yabo agbègbè Ahoro-Esinele nijoba ibile Oriire ni ipinle Oyo ti won si ji ọ̀gá àgbà iléèwé gírámà àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan ti a ko mo pàtó iye tí wọ́n jẹ́ báyìí ni wọ́n jí gbé lọ .
Gẹ́gẹ́ bi àlàyé ti ilẹ́eṣẹ́ ọlọ́pàá nipinlẹ Ọ̀yọ́ , ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé láàárín aago mẹjọ àárọ̀ sí aago mẹsan ọjọ Jimọ, ni iléèwé gírámà Community High School, Ahoro-Esinele.Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, DSP Ayanlade Olayinka, nínú ọrọ kan to fi sita ni ọjọ Jimọ, sọ pé àwọn agbébọn náà yabo iléèwé náà, ti wọn si ko awọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wọn ko tii fidi rẹ múlẹ̀ iye tí wọ́n jẹ́ lọ, pẹ̀lú ọga àgbà ileewe náà , Arabinrin Rachael Alamu. Àtẹ̀jáde náà ni “Àwọn agbébọn ti yabo ilu Ahoro-Esinele ni ìjọba ìbílẹ̀ Oriire ni ìpínlẹ̀ Ọyọ ti wọn ji ọga agba ileewe gírámà ati awọn. akẹ́kọ̀ọ́ ti a ko ti mọ pàtó iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé lọ. Gẹ́gẹ́ bi o ti sọ, olùgbé kan ròyìn pé àwọn agbebọn náà tun YÌNBỌN lu oluko kan lakoko ikọlu náà. Ó fi kún ọ̀rọ̀ pé olukọ kan ni ìbọn bà lakoko ìkọlù náà , botilẹjẹpe iwọn ipalara naa ko ti jẹrisi a kò ti mo bí ìpalára náà ṣe tó .
“Gẹgẹ bi iroyin náà ṣe sọ, awọn agbebọn náà salọ kuro nibi isẹlẹ náà pẹ̀lú ọga àgbà nínú ọkọ rẹ ti wọn si salọ sínú igbo ti o wa ni agbègbè náà .
Awọn olùgbé agbègbè náà sọ pe àgọ́ ọlọ́pàá ti o sunmọ julọ wa ti ko ijinna diẹ sibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí ṣẹlẹ̀ , eyiti o ṣe idaduro ìdáhùn lẹsẹkẹsẹ, ”o wi pe.Ọ̀gá ọlọ́pàá sọ pe Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ran awọn oṣiṣẹ lọ si agbègbè fún àyẹ̀wọ̀ ati lati lọ ṣe awọn iṣẹ ìgbàlà fún àwọn olùkọ́ àti ọmọ ilé ìwé .Ẹ gbìyànjú láti ka Awọn aláyè díẹ̀ sii nigbamii…[15/05, 15:19] ÀṢÀKẸ́ TV SHOW: Àwọn Agbéṣùmọ̀mí ti jí ọ̀gá àgbà àti àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ gbé lọ, ní ilé ìwé gírámà Ahoro – Esinele ní ìjọba ìbílẹ̀ Oriire ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní dédé ago mẹ́jọ sí ago mẹ́sàn àárọ̀ ọjọ́ Ẹtì.












Leave a Reply